2023: Ipo aarẹ Naijiria ko ti i le lọ sọdọ awọn ẹya Igbo bayii – Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe ṣe ni ki awọn ẹya Igbo mojuto ọrọ idagbasoke eto ọrọ-aje wọn, ki awọn naa le rọwọ mu ninu oṣelu orileede Naijiria.
Ọba Akanbi ṣalaye pe ko si ọmọ orileede yii ti yoo ni ifọkanbalẹ nigba ti aarẹ tabi aṣaaju ba gbe ẹya rẹ lori, ti ko si faaye gba awọn ẹya miiran lati ni ninu ilẹ wọn. O ni ti wọn ko ba wa ọna lati ṣatunṣe si eleyii, otubantẹ ni erongba wọn lati di aarẹ orileede Naijiria yoo jẹ.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, fi sita lorukọ ọba alaye naa lo ti sọ siwaju pe ọgbẹ ogun abẹle ṣi wa lara awọn ẹya Igbo, idi niyẹn to fi ni wọn gbọdọ tun ero wọn pa nipa fifaaye gba awọn ẹya miiran lati lanfaani si ilẹ lọdọ wọn.
O ni iwa naa ko jẹ ki wọn lagbara ninu oṣelu, bẹẹ ni ko si jẹ ki idagbasoke ba eto ọrọ-aje wọn nitori ibagbepọ oniruuru ẹya maa n mu ki agbegbe gberu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, oniruuru ẹya lo wa nilẹ Iwo, yatọ si pe wọn n ṣowo nibẹ, wọn tun n kọle, bẹẹ ni wọn n dako. O ni ko sibi ti wọn ko ti gbọdọ gba ẹya kan laaye lati ni ilẹ.

“Ko ṣee ṣe ki ẹni to wa lati ẹya ti wọn ti n dẹyẹ si awọn ẹya yooku to le di adari lorileede yii. Ti awọn Ibo ba jade kuro lagbegbe wọn, wọn aa da ileeṣẹ silẹ, wọn aa si kọle nla, ṣugbọn lọdọ tiwọn, ko si anfaani fun ẹya miiran lati ni ilẹ, iru iwa bayii maa n mu ifasẹyin ba agbegbe ni.”
Bakan naa ni Oluwoo bu ẹnu atẹ lu aṣẹ konilegbele ti wọn n ṣe nilẹ Ibo, o ni iru iwa ifiya-jẹra-ẹni naa ko le mu wọn tẹsiwaju, bẹẹ ni o le ṣakoba fun orileede lapapọ.
Ọba Akanbi ni, “Wọn tun kede konilegbele nitori orileede Biafra ti wọn n fe. Wọn ti ara wọn mọnu ile, wọn ko lọ sibiiṣẹ. Ẹ dakun, ṣe iyanu lo maa fun wọn lounjẹ? Ifiya-jẹra-ẹni laye ọlaju niyẹn.
“Ṣe ni ki wọn yẹ ara wọn wo ti wọn ba mọ pe awọn naa fẹẹ rọwọ mu ninu oṣelu ilẹ Naijiria.”

Leave a Reply