2023: Mo fi ori-ade bẹ ẹyin agbaagba Yoruba lati ma ṣe jẹ ki anfaani nla yii fo wa ru-Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdul Rosheed Adewale Akanbi, ti parọwa si gbogbo awọn adari ẹya Yoruba lati dariji ara wọn, ki wọn baa le lọ sinu idibo apapọ ọdun 2023 pẹlu iṣọkan.

Ọba Akanbi ni fun anfaani iran Yoruba, gbogbo wọn gbọdọ gbagbe ikunsinu to ba wa laarin ara wọn bayii, ki wọn si duro papọ lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe, ki irinajo naa le rọrun.

Ninu atejade kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, fi sita lorukọ kabiesi ni Ọba Akanbi ti ke si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati ṣan ṣokoto rẹ giri, ko si bẹrẹ si i bẹ gbogbo awọn agbaagba ti inu ba n bi nilẹ Yoruba.

O ni, “Mo n ke si gbogbo awọn aṣaaju ilẹ Yoruba, awọn lookọlookọ ati awọn oloṣelu lati tun itan ireti ati ti ọjọọwaju to dara kọ nipasẹ didariji ara wọn. Lai si idariji, ibaṣepọ ko le bi ọmọ ologo. Mo n fi ori-ade bẹ yin pe ki ẹ foju fo aṣiṣe ara yin, ki ẹ si ṣe ara yin lọkan nitori ọrọ Yoruba.

“Oloogbe Ọbafemi Awolọwọ gbiyanju. Lẹyin rẹ tun ni gbajugbaja oniṣowo nni, Moshood Kaṣimawo Abiọla gbiyanju, o si gba dẹmokiresi fun wa. A ko gbọdọ tun ṣe aṣiṣe kan naa. Eleyii ki i ṣe ọrọ ẹgbẹ oṣelu. O di dandan ka ṣẹ ara wa, ṣugbọn a gbọdọ le dariji tinutinu.

“Anfaani wa bayii, to si mọlẹ kedere, fun ọkan lara wa lati di aarẹ orileede Naijiria. O le ti ṣẹ yin bi ẹyin paapaa yoo ti ṣẹ eeyan kan. Ẹ jẹ ka gbe iṣọta ti sẹgbẹẹ kan ka baa le tete tẹsiwaju. Anfaani to gbẹyin leleyii ti a ba fẹ ki awọn ọmọ wa fori ji wa.

“Mo n rọ oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati lọọ ba awọn agbaagba Yoruba, awọn ti ọrọ yii kan ati awọn oloṣelu fun ipẹtusaawọ tootọ ati ifikunlukun. Gbogbo wa la gbọdọ ṣiṣẹ yii. O gbọdọ kari gbogbo ẹgbẹ oṣelu. Iṣẹ gbogbo wa ni fun iṣọkan Naijiria. O gbọdọ kọja ọrọ ẹgbẹ oṣelu.

“Oludije yii ni iriri pupọ, o si ni ọpọlọ pipe lati dari orileede Naijiria. Amuyangan lo jẹ fun orileede yii, gbogbo wa la si gbọdọ gbaruku ti i lati ṣafihan ijafafa rẹ gẹgẹ bo ṣe ṣe lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Eko

Leave a Reply