Ọwọ ọlọpaa tẹ ṣọja atawọn meji mi-in to ji akẹkọọ yunifasiti gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin ṣọja kan, Adeuyi Adeyayo ati awọn meji miiran, ti wọn lọọ ji ọmọ yunifasiti to wa ni Ọyẹ-Ekiti, FUOYE gbe.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, o ni meji lara awọn ajinigbe naa ti wọn wa lati ipinlẹ Ondo ati ọkunrin ṣọja naa to sọ pe ipinlẹ Yobe loun ti n ṣiṣẹ, ni wọn ti n da agbegbe Ọyẹ-Ekiti laamu lati igba diẹ.

Abutu ṣalaye pe awọn ọdaran naa ti orukọ wọn n jẹ Ọlajide Nathaniel, Ojo Babajide ati Adeuyi Adedayọ

lọwọ tẹ nileetura kan to wa ni Ado-Ekiti, nibi ti wọn fara pamọ si pẹlu ọmọ ti wọn ji gbe naa.

O ni lọsan-an ọjọ Abamẹta lawọn ọlọpaa sadeede gba ipe pe awọn agbebọn kan ti ji ọmọ yunifasiti kan gbe ni Ọyẹ-Ekiti, wọn si ti gbe e lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.

O ṣalaye pe bi wọn ṣe gba ipe naa tan ni awọn ọlọpaa Rapid Response Squad (RRS), bẹrẹ igbesẹ lati le ri awọn agbebọn naa mu.

O  ni ileetura kan ti wọn n pe ni Ifẹlodun, ni Ado-Ekiti, nibi ti wọn fi ọmọ yunifasiti naa si, ti wọn si n dunaa-dura bi wọn yoo ṣe gbowo ni ọwọ ti tẹ wọn.

Ọdun kẹta ni ọmọbinrin ti wọn ji gbe naa wa nileewe giga Fasiti Ọyẹ Ekiti, wọn ri i gba lọwọ awọn ajinigbe naa, wọn si mu wọn lọ.

Abutu ṣalaye pe gbogbo akitiyan ni ajọ ọlọpaa n ṣe lati le ri ọkan lara awọn agbebọn naa to ti sa lọ mu.

O fi kun un pe awọn ọdaran naa ti jẹwọ pe loootọ ni wọn ṣẹ ẹṣẹ naa, ti wọn ji ọmọ yunifasiti gbe ki wọn le gbowo lọwọ awọn obi rẹ.

 

Leave a Reply