Ileelẹ ti wọn fẹẹ sọ di alaja mẹta wo l’Ekoo, oku mẹrin ni wọn hu jade

Ileelẹ ti wọn fẹẹ sọ di alaja mẹta wo l’Ekoo, oku mẹrin ni wọn hu jade
Faith Adebọla, Eko

Titi dasiko yii, oku eeyan mẹrin ni wọn ti hu jade labẹ awoku ile alaja mẹta kan ti wọn n kọ lọwọ, lasiko ti ile naa rọ lulẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii, eeyan marun-un ni wọn wa nibi ti wọn ti n du ẹmi wọn lọwọ, latari bi wọn ṣe fara pa yanna-yanna lasiko ijamba naa.
Opopona Alayaki, l’Erekuṣu Eko, ni iṣẹlẹ naa ti waye laṣaalẹ ọjọ Satide, lasiko ti ojo arọọda kan n rọ l’Ekoo.
Ọga agba ajọ apapọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lagbegbe Guusu/Iwọ-Oorun, National Emergency Management Agency (NEMA) Ọgbẹni Ibrahim Farinloye, lo sọrọ yii di mimọ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, nigba to n sọ ibi ti iṣẹ idoola ẹmi de duro lori iṣẹlẹ ibanujẹ naa.
Farinloye ni: “A ṣẹṣẹ tun hu oku ọkunrin jade labẹ awoku naa ni, eyi ni oku kẹrin ta a hu jade. Eeyan marun-un la ri fa yọ laaye, wọn si ti wa nibi ti wọn ti n fun wọn nitọju pajawiri, tori gbogbo wọn lo fara ṣeṣe gidigigi.
“Lasiko ti iṣẹlẹ aburu naa fi waye, wọn n kọ ile naa lọwọ ni, wọn ti da kọnkere aja kẹta ile ọhun tan, awọn yara ti wọn fẹẹ kọ sabẹ rẹ ni wọn n to bulọọku si lọwọ, ṣugbọn ojo nla to n rọ lọsan-an titi dirọlẹ ọjọ naa lo faya ile naa balẹ lojiji.
“Ile ilẹ ni ile naa nigba ti wọn kọ ọ, awọn ọmọ to jogun ẹ ni wọn bẹrẹ si i tun un kọ, wọn fẹẹ sọ ọ di alaja mẹta.
“A o ti i ri ẹnikẹni ninu mọlẹbi awọn to ku ati awọn to fara pa yii o. Iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ, ṣugbọn a o raaye ṣiṣẹ naa daadaa, tori ibi tile naa wa ha gadigadi, ọna tooro lo wọ ibẹ, ibẹ ko faaye gba awọn ẹrọ wa lati ṣiṣẹ naa bo ṣe yẹ, ṣugbọn a n gbiyanju gbogbo iṣapa wa.”
Bakan naa ni ọga agba fun ajọ to ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA), Dokita Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu sọ ninu atẹjade mi-in to fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, pe, “ilana ti ko bofin mu lawọn to n kọle yii tẹle, wọn ko si gbaṣẹ lọdọ ijọba lati sọ ile naa di alaja mẹta.
“A ṣakiyesi pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ile kikọ ati eto ilu l’Ekoo, LASBCA, ti ṣabẹwo sagbegbe yii tẹlẹ, ti wọn si ti kọwe sawọn to n ṣiṣẹ ikọle nibẹ pe ki wọn dawọ iṣẹ duro, ṣugbọn wọn ko ṣe bẹẹ.
“Bakan naa ni wọn ti lọọ sami sara ile naa, ti wọn si takun di ibẹ, ṣugbọn niṣe lawọn oṣiṣẹ naa n ba iṣẹ wọn lọ, oru mọju ati opin ọsẹ ni wọn n yọ kẹlẹ ṣiṣẹ nibẹ, kawọn alaṣẹ ma baa fura tabi ri wọn mu.
Ko sẹni to mọ iye eeyan to wa labẹ awoku naa bayii, tori a o ri akọsilẹ kan nipa iye eeyan to n ṣiṣẹ ikọle lọwọ lasiko ti ijamba naa fi waye, a o si ti i foju kan awọn onile ati kọngila to gba iṣẹ ile kikọ naa, ṣugbọn a ṣi n ba iṣẹ idoola ẹmi lọ ni tiwa.”
Titi di ba a ṣe n sọ yii, iṣẹ aṣelaagun lawọn oṣiṣẹ ajọ NEMA, LASEMA, ileeṣẹ panapana, awọn ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ati tọlọpaa Eko, n ṣe nibi iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ si lawọn oṣiṣẹ eleto ilera ati awọn Red Cross n ṣeranwọ to yẹ.
Tẹ o ba gbagbe, nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni eeyan mẹwaa doloogbe ti ọpọ si di alaabọ ara nigba ti ile alaja mẹta kan da wo lọjọ Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ta a wa yii, lagbegbe Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko.

Leave a Reply