Mi o ni ikunsinu si gbogbo awọn to ṣiṣẹ ta ko mi lasiko idibo abẹle-Tinubu

Jọkẹ Amọri
Oloṣelu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati gbe asia ẹgbẹ APC lasiko idibo to n bọ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe oun ko ni ẹnikẹni sinu, bẹẹ loun ko ba gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ ta ko oun lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ja rara.
Tinubu ni oun ko ni i lọkan pe oun maa jawe olubori.
O waa sọ pe, ‘Ifigagbaga naa ti pari bayii o, mi o ni ikunsinu si ẹnikẹni. Ẹ jẹ ka fọwọsowọpọ lati gba ẹgbẹ PDP sigbo lasiko idibo to n bọ. Ọdun mẹrindinlogun ni wọn lo, ṣugbọn inu ebi ati aini ni wọn sọ wa si. Ẹ jẹ ka gbẹ saare wọn nipa jijawe olubori lasiko idibo ọdun to n bọ, nitori oniṣẹ ipọnju, aini, irọ, idunkooko-mọ-ni ati jagidijagan ni wọn.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn oludjie meje to juwọ silẹ fun un.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: