Oyebanji, igbakeji rẹ gba iwe-ẹri mo yege
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji ati Igbakeji rẹ, Arabinrin Monisade Afuyẹ, ti gba iwe-ẹri mo yege lati ọwọ ajọ eleto idibo, eyi to n tọka si aṣeyege wọn ninu eto idibo gomina to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Oyebanji ni ibo mẹtadinlaaadọwa o le diẹ (187,057) lati fẹyin oludije ninu ẹgbẹ Ẹleṣin, Oloye Ṣẹgun Oni, to ni ibo mejidinlọgọrin ati diẹ ni ibo (82,211) janlẹ.
Nigba to n sọrọ ni kete to gba iwe-ẹri naa tan ni ọfiisi ajọ eleto idibo l’Ado-Ekiti, lọjọ Wẹsidee, Oyebanji ṣeleri pe oun yoo mu gbogbo ileri ti oun ṣe fun ipinlẹ Ekiti lakooko ipolongo oun ṣẹ.
O sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe aṣeyege oun ninu eto idibo naa ki i ṣe fun oun nikan, ṣugbọn fun gbogbo alatilẹyin oun, o ṣeleri pe oun yoo ṣe agbakalẹ ijọba to mu irọrun ba gbogbo eeyan ipinlẹ Ekiti.
O dupẹ lọwọ ajọ eleto idibo pẹlu bi wọn ṣe pese aaye to dara silẹ fun eto idibo naa, o ṣalaye pe ṣiṣe agbekalẹ ẹrọ ti yoo maa ṣe idanimọ lakooko idibo ni ọna miiran pataki to mu eto idibo naa yọri si rere.
Oyebanji ṣeleri pe oun yoo ni ajọṣepọ pẹlu ajọ eleto idibo lati mu itẹsiwaju ba eto idibo orilẹ-ede Naijiria, o tun ṣeleri pe oun ko ni i dojuti awọn to dibo yan oun.

Kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ekiti, Dokita Adeniran Tẹlla, ṣalaye pe fifun Oyebanji ni iwe-ẹri wa ni ibamu pẹlu ofin idibo ọdun 2022, to sọ pe kọmiṣanna gbọdọ fun gomina ati igbakeji rẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni iwe-ẹri ko too pe ọjọ mẹrinla ti wọn ba ti dibo yan wọn.

Tella rọ gbogbo awọn eyan ipinlẹ Ekiti ki wọn fọwọsọwọpọ pẹlu ajọ eleto idibo.

Leave a Reply