Awọn ọlọpaa ti mu ọmọbinrin ti ọrẹkunrin ẹ ku sinu otẹẹli ti wọn jọ sun mọju

Monisọla Saka

Ọmọbinrin kan ni wọn lo ti ko si wahala lẹyin to rinrin-ajo wa si ipinlẹ Eko lati waa pade ọrẹkunrin ẹ to pade lori ẹrọ ayelujara.

Otẹẹli ni awọn mejeeji gba lẹyin tọmọbinrim naa de si Eko, ṣugbọn ọmọkunrin naa yọ ṣubu, o si gbabẹ dero ọrun lasiko to loun fẹẹ sare wọnu ile igbọnsẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, lo sọ eleyii di mimọ lori ayelujara Twitter rẹ, o ni niṣe lọmọbinrin naa n rawọ ẹbẹ pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn ma si ṣe jẹ ki awọn obi oun gbọ si i, ati pe, oun o mọwọ mẹsẹ ninu iku ọkunrin naa.

Hundeyin tẹsiwaju pe obinrin yii gbera wa si ipinlẹ Eko lati waa pade ololufẹ ẹ fun igba akọkọ ni, ki tọhun too yọ ṣubu. Obinrin yii ni wọn ti fi panpẹ ofin, gbe ti wọn si fi ẹsun ipaniyan kan an.

Nigba tawọn kan n da ọga ọlọpaa lẹbi fun fifẹsun ipaniyan kan ọmọbinrin naa lai si nibẹ nigba tọkunrin naa ku. ti wọn ko si ti i ṣayẹwo nile iwosan, awọn mi-in rọ wọn lati ṣe iwadii to daju ki wọn too foju ọmọbinrin naa han laarin awọn ọdaran fawọn oniroyin.

Hundeyin kilọ fawọn ọdọ lati ṣe pẹlẹ, ki wọn si jẹ ki awọn obi wọn maa mọ irin ẹsẹ wọn, ki wọn ma si ṣe gbero lati lọọ pade ẹni ti wọn o ba mọ ri nibi kọlọfin.

Leave a Reply