Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ agba funpinlẹ Ọṣun, Onidaajo Adepele Ojo, fi ibinu rẹ han si bi olujẹjọ akọkọ, Dokita Ramon Adedoyin, ko tun ṣe fara han ni kootu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, lati oṣu mẹta sẹyin ti wọn ti mu deeti.
Oni lo yẹ ki adajọ gbe idajọ kalẹ lori atunṣe ti ọfiisi agbẹjọro fun olupẹjọ, Fẹmi Falana (SAN), fẹẹ ṣe si awọn ẹsun ti wọn fi kan Adedoyin.
Dokita Adedoyin ati awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ni wọn n koju ẹsun oniruuru lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, sinu otẹẹli Hilton Ileefẹ lọdun to kọja.
Nibẹrẹ oṣu Keje ti igbẹjọ waye, ohun to yẹ ko waye ni ki adajọ dajọ lori gbigba akọsilẹ awọn agbẹjọro abala mejeeji, ṣugbọn Agbẹjọro Falana sọ fun kootu pe oun fẹẹ fi kun ẹsun ti wọn ka si Adedoyin lọrun.
Bayii ni wọn sun igbẹjọ siwaju, ṣugbọn lọjọ igbẹjọ to gbẹyin, Dokita Adedoyin ko wa, wọn sọ pe ojojo n ṣojo rẹ lọgba ẹwọn to wa, gbogbo awọn agbẹjọro to ku si fẹnu ko pe ki wọn mu ọjọ miiran fun idajọ.
Laago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ Iṣẹgun ni awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn too ko awọn olujẹjọ de, ṣugbọn ko tun si Dokita Adedoyin laarin wọn.
Nigba ti Onidaajọ Adepele Ojo wọle sinu kootu, ti awọn agbẹjọro fi ara wọn han, o beere idi ti Adedoyin ti i ṣe olujẹjọ akọkọ ko tun ṣe wa, Agbẹjọro Fatimah Adeṣina to duro fun Falana sọ pe oun gbọ pe ara rẹ ko ya ni.
Awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ keji, titi de ikeje, sọ pe pẹlu bi ko ṣe wa, ko si nnkan ti awọn le ṣe nitori agbekalẹ ofin ni pe olujẹjọ akọkọ gbọdọ wa ni gbogbo ipele idajọ, bo ti wu ko kere to, nitori ẹtọ rẹ labẹ ofin ni.
Eyii lo bi Onidaajọ Ojo ninu, o ni gbogbo ero ọkan oun ni lati pari igbẹjọ naa laarin oṣu mẹfa pere, ṣugbọn pẹlu oniruuru idaduro to n ṣẹlẹ bayii, wọn ti n fi asiko oun ṣofo.
O ni ohun meji lo ṣee ṣe ko waye nijokoo to n bọ, o ni o ṣee ṣe koun tu awọn olujẹjọ mẹfa to ku silẹ pẹlu fifaaye silẹ fun beeli wọn tabi ki oun gbe ẹjọ naa siwaju onidaajọ miran, nitori oun ko ni i pẹẹ fẹyinti lẹnu iṣẹ.
Nitori naa, o sun igbẹjọ si ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii, o si paṣẹ pe ki wọn mu akọsilẹ ileewosan nipa ilera Adedoyin wa ti wọn ba ti n bọ.
Ṣe ni awọn olujẹjọ yooku bu sẹkun nigba ti wọn gbọ eleyii, bẹẹ ni ko si agbẹjọro to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ.