Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni idarudapọ ṣi n wa niluu Ikirun agunbẹ onilẹ obi. Eyi ko seyin gbọnmi-si-i omi-o-to-o to n ṣẹlẹ lori ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan niluu naa, Ọba Ọlamilekan Akadiri. Wọn ni ijọba ko gba ọna to tọ yan kabiyesi, bẹẹ ni ko ṣe gbogbo etutu to yẹ gẹgẹ bii ọba. Wọn lawọn ko gba a gẹgẹ bii ọba awọn, nitori idile rẹ kọ lo yẹ ko fa ọmọ oye kale. Ni wọn ba sọ kọkọrọ sẹnu ọna aafin, wọn ti i pa. Bẹẹ ni wọn gbe oogun abẹnugọngọ siwaju aafin ọhun, wọn lẹni to ba sun mọ ibẹ, iku lo fi n ṣere.
Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, tijọba ipinlẹ Ọṣun kede Akadiri lati ile Ọbaara, gẹgẹ bii Akinrun tuntun ni ara ko ti rọ okun, ti ko si rọ adiyẹ niluu ọhun.
Ni kete ti ikede yii waye ni wahala nla ti bẹrẹ, awọn ọdọ atawọn agbalagba lobinrin ati lọkunrin fọn sita, wọn n fẹhonu han pe ki i ṣe Akadiri lo tọ si ipo naa, wọn ni ile Ọbaara lo yẹ ki Akinrun tuntun ti wa, sibẹ, awọn afọbajẹ yooku, yatọ si Eesa, jawe oye le Akadiri lori.
Bi awọn ti wọn n fẹhonu han ṣe n jawe kaakiri ilu pẹlu oniruuru orin ni wọn n sun taya si awọn ikorita to ṣe koko ninu ilu naa, koda lalẹ ọjọ naa, awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe eeyan marun-un lo fara gba ọta, ti wọn si n gba itọju lọwọ nileewosan.
Nigba to di ọjọ Satide to kọja, iyẹn ọjọ kẹta ti wahala naa ti bẹrẹ, awọn kan lọọ gbe aṣọ oogun abẹnugọngọ kọ si ara geeti to wọ aafin, to si mu ko nira fun ẹnikẹni lati wọbẹ.
Eesa ilu Ikirun, to tun jẹ olori awọn afọbajẹ ilu naa, Oloye Lawal Kareem, sọ fun ALAROYE pe gbogbo etutu to yẹ ki wọn ṣe fun Akinrun tuntun, Ọba Ọlamilekan Akadiri, ni wọn ko ṣe fun un.Ṣugbọn Oloye Kareem ṣalaye pe oun ko lọwọ ninu fifi Ọba Akadiri jẹ, bẹẹ ni wọn ko si ṣe gbogbo etutu to yẹ ko waye ko too di pe wọn yoo pe e ni ọba fun un.
O ni, “Rara o, emi o si lara awọn ti wọn jawe le e lori. Gbogbo etutu to yẹ ko ṣe, ile emi Eesa lo yẹ ki wọn ti ṣe e, odidi ọjọ mẹta lo yẹ ko fi wa nibi ko too di pe yoo lọ saafin, ṣugbọn eleyii ko waye.
“Wọn ko ṣe etutu kankan fun un. Gbogbo ilu Ikirun ni wọn sọ pe awọn ko fara mọ ọba tuntun yii. Awọn kan ti wa ni aafin ti wọn n ṣọ aafin. Ẹ jẹ ka maa wo nnkan ti yoo ṣẹlẹ nigbẹyin.“
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, oludari ajọ kan ti ko rọgbọku le ijọba, Dialogue 365, Saka Waheed, ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun lati fi eti si aroye awọn araalu, ki wọn si wa ọna ti alaafia yoo fi pada si ilu Ikirun.
Bakan naa lo ke si awọn araalu lati ma ṣe ṣedajọ lọwọ ara wọn, o ni anfaani wa fun ẹnikẹni ti inu ba n bi lati lọ si kootu lati yanju ohunkohun to ba n bi wọn ninu.
Amọ ṣa, igbimọ Akinrun, iyẹn Akinrun-In-Council, ti ke si gbogbo awọn ti inu wọn ko dun si bi wọn ṣe yan ọba tuntun naa lati ni ṣuuru, ki wọn si gbe ọrọ naa gba ọna to tọ.
Titi di ba a ṣe n sọ yii, gbọn-in gbọn-in ni wọn ti ilẹkun aafin, ti wọn si so aṣọ oogun mọ ẹnu ọna ibẹ, bẹẹ lawọn ọdọ kan wa nibẹ ti wọn n ṣọ ọ, ti wọn ko si gba ẹnikẹni laaye lati wọ ibẹ.