Iya ọlọmọ marun-un dawati n’Ibafo

Faith Adebọla

Iyaale ile kan, Abilekọ Rosemary Obidinma, ti dẹni awati lagbegbe Ibafo, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun, latari bi wọn ṣe lobinrin naa jade lọ sibi iṣẹ aje rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, ṣugbọn to jẹ alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ titi di ba a ṣe n sọ yii.

A gbọ pe iya ọlọmọ marun-un naa ba akọbi ẹ, Daniel, sọrọ lori aago ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa, o lo ti kuro ni ṣọọbu oun l’Apapa to ti lọọ ṣọrọ-aje, oun ti n dari bọ nile, ọna loun wa, oun si ni i pẹẹ de mọ, ṣugbọn igba ikẹyin ti wọn gbohun rẹ gbẹyin niyẹn.

Lọjọ keji tawọn mọlẹbi tun pe aago obinrin ọhun lati mọ ibi to wa, wọn lọkunrin agbalagba kan lo gbe e, ọkunrin naa si kilọ fun wọn pe ki wọn yee yọ oun lẹnu, tori ipinlẹ Delta loun wa ni toun.

Daniel sọ fakọroyin Punch pe inu sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ, lọna marosẹ Eko s’Ibadan ni mama oun loun wa nigba toun ba a sọrọ lẹyin to jade nile laaarọ ọjọ naa, nigba toun ati aburo oun si ba a sọrọ ni nnkan bii aago mejila, wọn ti de sọọbu wọn l’Apapa.

Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ tọmọ naa tun pe iya ẹ lori aago, o ni oun ti ṣiwọ ọja ọjọ naa, oun ti tilẹkun ṣọọbu oun, oun ti n bọ. Igba toun tun pe e, o loun wa ninu ọja Ketu, oun bọọlẹ nibẹ lati ra nnkan ọbẹ tawọn maa se toun ba de.

Nigba ti wọn reti Roseline di aago mọkanla alẹ ti wọn ko ri i, wọn pe nọmba ẹ, ko lọ, wọn ti pa a. Lọjọ keji lo di pe ọkunrin kan lo bẹrẹ si i dahun aago naa, niṣe lọkunrin naa si n fesi pe nọmba tawọn n pe ki i ṣe ti mama wọn o, toun ni, wrong number lọkunrin naa n sọ fun wọn lede eebo, ko too di pe o jagbe mọ wọn lati da wọn lẹkun pipe oun.

Wọn ni wọn ti fọrọ yii to awọn agbofinro leti ni teṣan Ibafo.

A tẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, laago lati gbọ tẹnu ẹ lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn titi ta a fi ko iroyin yii jọ, ko ti i fesi si ipe wa.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni iṣẹlẹ ijinigbe tun di lemọlemọ lọna marosẹ Eko s’Ibadan, nigba ti wọn ji Ọjọgbọn Ajagbe atawọn akẹkọọ Poli Abẹokuta kan gbe. Obitibiti owo ni wọn gba ki wọn too tu wọn silẹ lẹyin ọjọ diẹ.

Leave a Reply