Kukah ta si Buhari: O ti ba Naijiria yii jẹ jinna ju bo o ṣe ba a lọ
Faith Adebọla
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii ọrọ ikini-ku-oriire, amọran ati iṣiri lawọn eeyan fi n ranṣẹ si ara wọn layaajọ ọdun Keresi, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjila, ọdun 2022 yii, ti eyi ko si yọ Olori orileede wa, Muhammadu Buhari, silẹ. Amọ ọrọ ẹdun-ọkan ati aidunnu ni Biṣọọbu ijọ Katoliiki, ẹka tilu Sokoto, Ẹni-ọwọ Matthew Kukah, fi ṣọwọ si Aarẹ o, o loun ba a dupẹ pe ilera ẹ ti gbe pẹẹli si i latigba to ti gori aleefa Naijiria, amọ o ba oun lọkan jẹ pe otubantẹ ni gbogbo ileri mọran-in mọran-in to ṣe fawọn ọmọ Naijiria lọdun 2014 ki wọn too dibo yan an ni 2015 ja si, o ni ipo ti orileede naa wa bayii balumọ gidi ju bi aarẹ wa ṣe ba a lọdun 2015 to gbajọba lọ.
Ninu ọrọ ikini ọdun Keresi to fi lede lọjọ Sannde naa, eyi to pe akori rẹ ni: “Naijiria: Ẹ jẹ ka bẹrẹ igbe aye ọtun,” Ojiṣẹ Ọlọrun naa ni amọran gidi toun le gba gbogbo ọmọ orileede yii ni ki wọn tẹwọ adura s’Ọlọrun, ki iru iṣejọba Buhari yii jẹ afimọ lorileede yii, o ni ki gbogbo wa pa oju-iwe de lori ẹ ni, ka ṣi iwe mi-in si abala ọtun lẹyin tijọba yii ba kogba sile laipẹ.
Lara ọrọ ti Kukah sọ ni pe:
“Aarẹ wa, mo ki ọ kuu ajọyọ ọdun Keresimesi o, ọdun aa yabo fun’wọ ati idile rẹ o. Ọrọ ti mo n sọ yii, mo n sọ ọ fun ara mi, mo si tun gbẹnu sọ fawọn ọmọ Naijiria lati ba ọ dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ilera rere pada sagọọ ara rẹ. A mọ pe ilera rẹ ti sunwọn lasiko yii ju ti atẹyinwa lọ, o ti han ninu irinsi rẹ, bo o ṣe n gbesẹ kanmọ-kanmọ, ati bo ṣe ṣee ṣe fun ọ lati maa lọ kaakiri agbaye, titi de awọn orileede to jijinna rere loke-okun. Ki Ọlọrun tubọ fun ọ lẹmii gigun ninu ilera o.
“Bawo ni iba ṣe dun to ka ni ọpọ miliọnu awọn ọmọ orileede yii naa lanfaani lati gbadun iru ilera to o jere yii, koda bo tiẹ jẹ iwọnba diẹ irufẹ ilera bẹẹ, nipa pipese eto ilera to muna doko siluu wa. O ba ni lọkan jẹ pe pẹlu awọn ileri amọkanyọ to o ṣe, ipo to o maa fi awọn ọmọ orileede yii silẹ si laipẹ, buru ju bi wọn ṣe wa ko o too de lọ, iwa ajẹbanu ta a lero pe o maa fopin si to o ba dori aleefa, niṣe ni ikowojẹ tubọ ta gbongbo, bẹẹ ni ojooro ati ojuṣaaju ninu iyannisipo rẹ di ilọpo ilọpo.
‘‘Ninu iṣẹ ikini ọdun Keresi to kọja, mọ tọka si i fun ọ pe bo o ṣe yan awọn olori ẹka iṣẹ ọba sipo ko bofin mu, o tẹ ilana pin-in-re la-a-re to wa ninu iwe ofin ilẹ wa, eyi ti wọn n pe ni federal character, loju, sibẹ titi doni, arun oju ni, ki i ṣarun imu, gbogbo wa la ri ohun to n ṣẹlẹ.”
Kukah tun kan Aarẹ Buhari nikoo lori bi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, rẹ ṣe fa oludije funpo aarẹ ati igbakeji ti wọn jẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa kalẹ, o ni: “Mo gbagbọ pe o mọ si bi ẹgbẹ oṣelu rẹ (APC) ṣe fa oludije ati igbakeji ẹlẹsin kan naa kalẹ, ṣugbọn oo ri nnkan kan ṣe si i. Sibẹ, ẹ ni ka maa gbadura fun eto idibo to mọyan lori, to wa deede, ti yoo si lọ geere.”
Ojiṣẹ Ọlọrun naa rọ awọn ọmọ orileede yii lati ma ṣe sọ ireti nu, o ni ki wọn pinnu lati yan olori to maa mu atunṣe rere ba orileede wa, ti yoo yọ awọn ogo wẹẹrẹ atawọn obi wọn ti wọn ti ha sigbekun awọn ajinigbe atawọn eeṣin-o-kọ’ku kuro, ti yoo si wo ilẹ wa san.
O lorileede yii gbọdọ ronu lori lati fi iyatọ saarin awọn ẹni iyi, ti wọn jẹ oloootọ, atawọn ti wọn ti jingiri sinu iwa ibajẹ, bẹẹ lo si ṣekilọ pe gbogbo ma a dogun, ma a dọgbọn ileri awọn oloṣelu ti wọn n polongo ibo, ki wọn ronu ara wọn lẹẹmeji nipa ẹ, ki wọn si fi ti Buhari yii kọgbọn.