Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹkun lọpọlọpọ idile fi bẹrẹ ọdun tuntun yii niluu Akinmọọrin, nijọba ibilẹ Afijio, nipinlẹ Ọyọ, pẹlu bi ọkunrin baaba kan to n jẹ Francis ṣe muti yo, to si mọ-ọn-mọ fi mọto kọ lu eeyan mẹwaa, ti marun-un ninu wọn si jẹ Ọlọrun nipe lọjọ ọdun tuntun, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
Laaarọ kutu ọjọ naa niṣẹlẹ ọhun waye laduugbo ti wọn n pe ni Baba Ọdẹ, niluu Akinmọọrin, nitosi Ọyọ Alaafin.
Mẹrin ninu awọn ti ori ko yọ lọwọ iku ijanba mọto ọjọ ọdun tuntun yii paapaa ni wọn wa nileewosan bayii nitori ti wọn fara pa yannayanna.
Yatọ si pe ọkunrin apaayan yii mọ-ọn-mọn huwa odoro ọhun, ohun to tubọ ṣe ni ni kayeefi nipa iṣẹlẹ yii ni pe ọrẹ ẹ lo pọ ju ninu awọn to finnu-findọ pa laaarọ kutu ọjọ ọdun naa.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nibi ti awọn ọrẹ ẹ yii ti n ṣariya lọwọ fun ọdun tuntun to ba wọn laye, ni Francis ti wa ọkọ ayọkẹlẹ rẹ de pẹlu ere asapajude.
Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe ọkunrin yii ti muti yo. Eyi lo fa a to fi sare wọ aarin awọn ọrẹ ẹ to n ṣariya ọdun, ṣugbọn ti ọrọ naa bọ sapo ibinu ẹ nigba ti awọn eeyan naa kilọ fun un pe ko yee fi ọkọ sa iru ere buruku bẹẹ, paapaa, lasiko ti awọn ọmọlẹyin Jesu ṣẹṣẹ n dari bọ lati iṣọ oru aisun ọdun tuntun.
Ọgbẹni Iyiọla, ọkan ninu awọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣalaye pe, “Nibi ti wọn ti n ba ara wọn fa a lọwọ lọkunrin ọdaran yii ti leri pe fun bi wọn ṣe pe oun nija yii, oun yoo fi bi oun ṣe jẹ han wọn, ẹjẹ yoo si ṣan nilẹ rẹpẹtẹ.
“Awọn agba adugbo ni wọn pẹtu si ọrọ yẹn to fi gba lati kuro laarin awọn ti wọn jọ n ja yẹn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ti wọn bẹ ẹ.
“Ṣugbọn bo ṣe wọ inu mọto rẹ, to ṣina fọkọ, lo tun bẹrẹ ere asapajude to tun lagbara ju takọkọ lọ. Aarin awọn ero to n ṣariya ọdun gan-an lo waa doju kọ, to si fi ọkọ gun gbogbo wọn lori mọlẹ”.
Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe iṣẹ baaba ni Francis n ṣe niluu Jobele, ṣugbọn bii ẹlẹ́dà lo ṣe maa n nawo, eyi to mu ki ọpọ eeyan gba pe jibiti lilu ti wọn n pe ni Yahoo gan-an lo n ṣe to fi n rowo to n na.
Ọmọ bibi ilu Jobele ni, ṣugbọn o fẹran lati maa gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lọọ ṣe faaji laduugbo Baba Ọdẹ, niluu Akinmọọrin. Owo to maa n na daadaa fawọn ọdọkunrin ẹgbẹ ẹ nibi faaji yii lo sọ pupọ ninu wọn dọrẹ ẹ ko too di pe ija ṣẹlẹ laarin wọn lọjọ ọdun, nigba ti jangulabi muti yo tan.
Mẹta ninu awọn ọrẹ ẹ ti wọn jọ wa lati Jobele ni wọn wa pẹlu ẹ ninu ọkọ rẹ naa. Atoun atawọn ọrẹ ẹ mẹtẹẹta ni wọn si ti na papa bora bayii lẹyin ti wọn ti fi mọto pa awọn ẹni ẹlẹni tan, ti wọn si ti ṣe awọn mi-in leṣe kalẹ rẹpẹtẹ.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe “wọn ti fi iṣẹlẹ yẹn to wa leti, iwadii to lagbara si ti bẹrẹ lori ẹ nitori CP Adebọwale Williams (ọga agba awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ) ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa ti wọn n tọpinpin iṣẹlẹ ipaniyan lẹka ileeṣẹ wa to wa ni Iyaganku, n’Ibadan ṣe iṣẹ naa kiakia”.