L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Alaaji Atiku Abubakar, yoo kopa nibi apero kan ti ẹgbẹ Idagbasoke Yoruba (South West Development Stakeholders Forum) ṣeto rẹ, eyi ti yoo waye ni Jogor Centre, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ọlalekan Ajia, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ lori eto naa.
‘‘Atiku atawọn oludije funpo aarẹ mi-in ta a ti fiwe pe yoo bawọn alẹnulọrọ ti ọrọ ilẹ Yoruba jẹ logun sọrọ, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, lai fi tẹgbẹ oṣelu ṣe, awọn adari ẹsin ati ẹya, titi kan awọn ẹgbẹ to ṣoju awọn ọmọ Naijiria lẹyin odi ni yoo wa nikalẹ. Ijiroro naa yoo da lori bi ọkọọkan wọn yoo ṣe ṣeranwọ fun ẹkun Guusu Iwọ-Oorun lori eto irinna reluwee to kale-kako, ipese ina ẹlẹntiriiki, eto aabo to jiire, ati idagbasoke awọn nnkan amuṣọrọ gbogbo, eyi ti yoo tubọ mu ki anfaani ati igbaye-gbadun awọn eeyan agbegbe naa pọ si i, gẹgẹ bo ṣe wa lakọọlẹ ninu eto Development Agenda for Western Nigeria (DAWN). Awọn ipinlẹ mẹfa ilẹ Yoruba ni wọn pawọ-pọ da DAWN silẹ lati ri si ọrọ idagbasoke, eto aabo, ajọṣe ati ọrọ-ọje agbegbe naa.
‘‘Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, ni oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Redemption Party (PRP), Kọla Abiọla, ati ti ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC), Ọmọyẹle Ṣoworẹ, yoo sọrọ nibi apero naa. Bakan naa, Ọmọọba Adewọle Adebayọ ti ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) yoo wa nikalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, nigba ti Alaaji Rabiu Kwankwaso ti ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party yoo wa nibẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.’’
Alaga ẹgbẹ ldagbasoke Yoruba yii (SWDSF), ti ko si fun oloṣelu kankan tabi gbe sẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan yii, Ọgbẹni Alao Adedayọ, sọ pe igbesẹ n lọ labẹnu lati mọ ọjọ pato ti oludije funpo aarẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati tẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi, yoo yọju.
Adedayọ ni iha Guusu/Iwọ-Oorun ni eto okoowo, ileeṣẹ ati ọrọ-aje Naijiria sodo si, tori bẹẹ, o tọ, o si yẹ, lati gbọrọ taarata lẹnu awọn oludije wọnyi nipa bi wọn ṣe fẹẹ mojuto ọrọ agbegbe naa ninu erongba wọn, ki Naijiria le wa lalaafia, niṣọkan, ko si ni ilọsiwaju.
Lara awọn ẹgbẹ mi-in to papọ sinu Ẹgbẹ SWDSF ni: Yoruba World Centre, Yoruba Kọ’ya Leadership & Training Foundation, Majẹobajẹ, Professional Women’s Group, ODUACCIMA, Ẹgbẹ Ọmọ Yoruba in North America, Association of Yorubas in Diaspora South Africa, Ọranmiyan Hunters Association, Farmers Groups, Town Development Unions atawọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba mi-in loke okun, titi kan ẹgbẹ awọn ọmọwe, awọn ontaja atawọn olokoowo gbogbo.
Ọlalekan Ajia
Agbẹnusọ fun SWDSF
Foonu: 08099924318
Imeeli: olalekan.ajia@gmail.com