Nitori to fẹ iyawo keji, baale ile kan dero ile-ẹjọ

Monisọla Saka

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, nileeṣẹ ọlọpaa wọ ọkunrin kan, Ọgbẹni Edmund Uzoma, lọ siwaju ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, lori ẹsun pe o fẹyawo keji.

Ẹsun mẹta ọtọọtọ ti wọn fi kan Uzoma niwaju Adajọ Adeọla Ọlatunbọsun ni pe o fẹyawo ẹlẹẹkeji to ta ko ofin igbeyawo alarede to ba iyawo ile ẹ ṣe, bẹẹ lo tun parọ lori awọn nnkan to wa ninu akọsilẹ to ṣe lasiko to n ṣe igbeyawo ẹlẹẹkeji ati iwe-ẹri igbeyawo wọn.

Agbefọba, Idowu Ọṣungbure, ṣalaye fun ile ẹjọ pe pẹlu bo ṣe jẹ pe Uzoma niyawo sile, o tun lọọ ṣegbeyawo alarede pẹlu obinrin kan to n jẹ Sophia Yongxian. O fi kun un pe, olujẹjọ tun parọ niwaju ile-ẹjọ to so oun ati Sophia papọ pe apọn loun, oun ko niyawo ri, bẹẹ loun ko ni obinrin kankan sile lasiko naa.

Lati ọdun 2019 ni Ọṣungbure sọ pe Uzoma ti ṣe aṣemaṣe ọhun, ati pe ijiya wa fun iru ẹṣẹ yii labẹ abala ikarundinlọgọfa ati irinwo-o-le-mọkanla iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko ati ọtalelọọọdunrun-o-le-mẹwaa iwe ofin ilẹ Naijiria, ti ọdun 2004.

Ninu ẹsun ti adajọ ka jade lo ti ni, “Pe iwọ Edmund Uzoma, to n gbe lagbegbe Lekki Road 15, Golden Gate Apartment, nipinlẹ Eko, ṣẹ si ofin pẹlu bo o ṣe lọọ ṣegbeyawo ẹlẹẹkeji ati irọ to o pa ninu awọn akọsilẹ to o ṣe lasiko ti wọn n so iwọ ati obinrin keji yii pọ”.

Olujẹjọ rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe oun ko jẹbi, Adajọ Ọlatunbọsun faaye beeli silẹ fun un pẹlu miliọnu kan Naira. O ni ko san miliọnu kan Naira gẹgẹ bii owo beeli ara rẹ, pẹlu oniduuro meji.

O tẹsiwaju pe ọkan ninu awọn oniduuro mejeeji naa gbọdọ ni ilẹ nipinlẹ Eko.

O waa sun igbẹjọ si ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply