Wọn ka agbari eeyan mọ Abdulrahman lọwọ, o lẹgbẹẹ titi loun ti ri i

Faith Adebọla

Ọrọ ti o jọra wọn ni afurasi ọdaran ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan n sọ nigba ti wọn bi i leere pe nibo lo ti ri agbari ati eegun iha eeyan ti wọn ba lọwọ ẹ, ki lo si fẹẹ fi wọn ṣe, o kọkọ loun loun ni i, igba to ya lo tun ni oun ri wọn he lẹgbẹẹ titi ni, ni wọn ba taari ẹ sakolo awọn ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiọdun, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Keji yii, lawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran naa ni ile to n gbe lagbegbe Banana, nijọba ibilẹ Borgu, nipinlẹ Niger. Olobo kan lo ni o ta awọn pe ọkunrin naa lẹbọ lẹru, awọn si fimu finlẹ nipa ẹ, ko too di pe wọn ri i mu.

Abiọdun ni ọmọ bibi abule Gbesewona, lorileede Olominira Bẹnnẹ, lafurasi yii. Nigba ti wọn lọọ ka a mọle, ti wọn ṣayẹwo gbogbo kọrọ iyara ẹ ni wọn ri korofo agbari eeyan kan, eegun iha mẹta, ere oriṣa to n tapo si lori meji, oogun abẹnugọngọ ati ẹgbẹrun marun-un owo ti wọn n na lorileede Benin, 5000 CFA.

Nigba tawọn ọlọpaa beere bọrọ ṣe jẹ lọwọ ẹ, wọn l’Abdulrahman jẹwọ pe oun loun ni gbogbo nnkan ti wọn ba wọnyẹn, oun n lo wọn ni, dukia oun si ni wọn.

Amọ nigba ti wọn tun tọpinpin siwaju lo tun ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni “mo rin irinajo lọ sorileede mi, Bẹnnẹ, laipẹ yii. Lọjọ ti mo n dari bọ, ti mo wọ Naijiria, mo taju kan-an ri baagi kan lẹgbẹẹ titi, ni mo ba duro, mo ro pe boya o ja bọ lọwọ ẹnikan ni tabi boya o re bọ lori ọkọ, ni mo ba gbe e, nigba ti mo si tu u wo, agbari eeyan ati awọn egungun ni mo ba nibẹ.

“Iru awọn nnkan wọnyi wulo femi, tori iṣẹ awo lemi n ṣe, a maa n lo awọn nnkan bawọnyi fun awure ati etutu, eyi ni ko jẹ ki n ro o lẹẹmeji, niṣe ni mo di baagi naa sẹyin ọkada ti mo n gun bọ, ti mo gbe e wale mi.”

Wọn tun beere lọwọ pe ki lo de ti ko fi lọọ sọrọ ọhun fawọn agbofinro, wọn lo fesi pe ewo lo kan awọn agbofinro ninu korofo agbari eeyan toun ri he, to si wulo foun, o loun o ro pe o pọn dandan lati lọọ sọ iru nnkan bẹẹ loun ko ṣe lọ.”

Ṣa, wọn ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Niger ti paṣẹ fawọn olutọpinpin lati wadii afurasi naa wo daadaa. Lẹyin iwadii ni wọn lawọn yoo taari oun ati ẹsibiiti ọwọ ẹ siwaju adajọ, kile-ẹjọ le da sẹria fun un.

Leave a Reply