Iya to fẹẹ la awọn ọmọ rẹ meji to n ja fori gba ada, lo ba gbabẹ ku

Adewale Adeoye
Awọn agba to sọ pe, ‘olulaja lo n fori gbọgbẹ’, ko parọ o, iyaale ile kan, Abilekọ Zainab Ibrahim, lo ti fiku ṣefa jẹ bayii nibi to ti n laja to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ rẹ meji kan, Inusa ati Usman, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lagbegbe Kpaduma, ni Kansu Asokoro, niluu Abuja lọhun.
ALAROYE gbọ pe gbara tawọn ọmọ iya mejeeji naa ti n bara wọn ja pẹlu ohun ija oloro, loju oloogbe naa ko ti gba a mọ, to si n pariwo pe kawọn aradugbo ti wọn wa nitosi waa ran oun lọwọ, ṣugbọn ti ko sawọn eeyan nitosi to le laja aarin awọn ọmọ naa.
Ohun ta a gbọ ni pe gbara ti oloogbe naa bẹ saarin awọn ọmọ rẹ mejeeji ti wọn n ja naa ni Inusa ti ṣeeṣi fi ada ọwọ rẹ bẹ iya rẹ lapa, ti ẹjẹ si n da gidi lara iya naa, kia ni wọn tete gbe e lọ si ọsibitu aladaani kan fun itoju, ṣugbọn bi wọn ti ṣe gbe e de ọsibitu, lawọn dọkita ti wọn ba lẹnu iṣẹ lọjọ naa sọ pe oku ni wọn gbe wa, ti wọn si ba wọn tọju rẹ si mọṣuari.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, Josephine Adeh, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe owuyẹ kan lo waa fọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, tawọn si ti lọọ fọwọ ofin mu Usman to jẹ ẹgbọn Inusa naa bayii.
O ni, ‘Ohun tawọn ọlọpaa gbọ ni pe ija nla kan lo bẹ silẹ laarin awọn ọmọ iya meji kan, Inusa ati Usman, ọwọ ẹgbọn dun aburo daadaa, bi wọn ṣe n ja ni oju iya wọn ko gba a rara, paapaa ju lọ, nigba to ti dọrọ pe wọn n yọ ohun ija oloro lati fi bara wọn ja. Ariwo pe ki awọn araadugbo gba oun ni iya awọn ọmọ naa n pa, ṣugbọn ko sẹnikankan nitosi rara, nigba ti oju iya naa ko gba a mọ, lo ba ko si wọn laarin, ṣugbọn ṣe ni Inusa to ti jẹya daadaa ba gbiyanju lati fada ọwọ rẹ ṣa Usman pa, bo ṣe ṣeeṣi lọọ fi ṣa iya rẹ lapa niyẹn, ti iya naa si ku, ko too di pe wọn gbe e de ọsibitu fun itọju rara, awọn dokita ni ẹjẹ ti da silẹ ju lara iya naa ko too di pe wọn gbe e de ọdọ awọn.
‘‘Inusa to ṣa iya rẹ pa ti sa lọ bayii, ṣugbọn a ti fọwọ ofin mu Usman, o si ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa agbegbe naa, nibi to ti n ran wa lọwọ lati mọ ohun to dija silẹ laarin awọn mejeeji’’.
Ni ipari ọrọ rẹ, Alukoro ni tawon ba ti ri Inusa mu lawọn maa foju awọn mejeeji bale-ẹjọ.

Leave a Reply