Adewale Adeoye

Ọgba ẹwọn ni adajọ ile-ẹjọ Sharia kan nipinlẹ Kano, Onidaajọ Sani Tanimu Sani Hausawa, ni ki wọn lọọ ju ọgbẹni kan to n gbe lagbegbe Dorayi, nijọba ibilẹ Gwale, nipinlẹ Kano, si.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe, o da ọgbọn buruku kan lati gba iyawo araale rẹ nibi to n gbe lọwọ ọkọ rẹ, to si n ba a sun bo ṣe wu u ko too di pe ọwọ ofin tẹ ẹ bayii.

ALAROYE gbọ pe agboole kan naa ni ọgbẹni naa pẹlu awọn tọkọ-taya yii n gbe, ṣugbọn ti ọgbẹni naa n fa oju iyawo ile naa mọra, to si n ṣeleri oriṣiiriṣii fun un pẹlu ẹtan, eyi to mu ki iyẹn ba ọkọ rẹ ja lori ohun ti ko to nnkan.

Nigba ti ọkọ iyawo paapaa si ti n fnra siyawo rẹ tẹlẹ pe ifẹ ikọkọ kan n lọ laarin oun ati alajọgbele wọn yii lo ba kuku jọwọ rẹ silẹ, to si ko eru rẹ jade kuro ninu ile ti wọn jọ n gbe.

Bi baale ile yii ṣe ko kuro nile ni ọkunrin to n yan iyawo rẹ lale fun un ni ọkan lara awọn yara to ṣi silẹ ninu ile ọhun lati ko gbogbo ẹru rẹ si. Ninu yara naa lo si ti n ba a sun nigba yoowu to ba fẹẹ ba a laṣepọ.

Ọlọpaa olupẹjọ fẹsun kan ọgbẹni naa pe iwa radarada rẹ gan-an lo mu ki ọkọ iyawo naa jawe ikọsilẹ fun iyawo rẹ, sugbọn ti ọgbẹni yii gboju-gboya, to si gba iyawo ile ọhun sinu ile, to si n fẹ ẹ lọ. Awọn ẹsun ọhun ni wọn sọ pe ki i ṣe ohun to daa rara, paapaa ju lọ ninu ofin ẹsin Islam ti i ṣe Sharia.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Sani ni ki wọn lọọ ju ọgbeni naa sọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi tun waye lori ọrọ rẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Ṣao, o ni wọn le tu u silẹ to ba ri ẹni to lorukọ gidi laairn ilu to maa ṣoniduuro fun un.

Samuel n rin ni bebe ẹwọn, dọkita lo n pe ara rẹ fawọn araalu

Leave a Reply