Awọn ọmo Oodua ni Kwara ati Kogi fẹẹ darapọ mọ awọn eeyan wọn nilẹ Yoruba

Aderounmu Kazeem

Awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa ni ipinlẹ Kwara ati Kogi ti kọwe si ile igbimọ aṣofin agba lati beere fun ẹtọ didarapọ mọ awọn eeyan wọn nilẹ Yoruba yooku. Wọn ni ki wọn ṣe atunṣe si aala ilẹ ni agbegbe mejeeji, ki awọn le bọ si aarin awọn ọ̄o baba awọn.
Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba to wa ijọba ibilẹ meje ni Kwara, ti marun-un wa ni Kogi, ni wọn panupọ sọrọ yii lọjọ Ẹti, Fraidee, to kọja pe awọn ti kọwe ranṣẹ sí ile igbimọ aṣofin agba, ti awọn si sọ pe yoo wu awọn ti ijọba ba le ṣe atunṣe si eto aala ilẹ, eyi ti yoo fun awọn lanfaani lati wa lara awọn ilẹ Yoruba yooku ni Naijiria.Orukọ ẹgbẹ wọn naa ni Kwara South Consultative Forum.

Ninu ọrọ Aarẹ ẹgbẹ naa, Alagba Joseph Aderibigbe, ẹni to jẹ akọwe agba akọkọ fun ijọba ipinlẹ Kwara lọdun 1967, o ni iwe awọn ti wa nile igbimọ aṣofin agba, ohun tawọn si fẹ ni bi gbogbo aye yoo ṣe maa ri awọn Yoruba tó wà ní Kwara àti Kogi bi Yoruba tootọ, tawọn eeyan awọn ti wọn wa ni iha Iwọ-oorun Naijiria yoo si mọ pe ọkan naa làwọn n ṣe.

Bẹẹ gẹgẹ ni won tun bẹbẹ pe inu awọn yoo dun ti awọn naa ba ni eto iṣakoso to dara bii tawon ilẹ̀ Yorùbá yooku lawọn agbegbe ti ori da wọn si. Ati pe yoo jẹ ohun idunnu ti awọn Yoruba to wa ni ìjọba ibilẹ marun-un ni Kogi ba le wa labẹ akoso awọn Yoruba Kwara, eyi ti yoo fí wọn han gẹgẹ ọkan lara awọn ẹya Yoruba ti wọn n gbe nilẹ Yoruba.

 

 

Leave a Reply