Laipẹ rara, ara maa tu awọn ọmọ orileede yii – Ijọba apapọ 

Adewale Adeoye

Oṣi to ṣẹ ọmọ f’ogun ọdun, iya to jẹ ọmọ f’ọgbọn oṣu, bi ko ba pa ọmọ, o gbọdọ dẹyin lẹyin rẹ ni. Laipẹ, lai jinna rara, ara maa too bẹrẹ si i tu awọn eeyan orileede yii, ti nnkan si maa pada ṣẹnuure fun tẹru-tọmọ’ Eyi lọrọ akin ati iyanju to n jade lẹnu Minisita fun eto iṣuna ati eto ọrọ-aje lorileede yii, Ọgbeni Atiku Bagudu.

Nibi eto pataki kan to waye laipẹ yii niluu Abuja ti i ṣe olu ilẹ wa ni minisita ọhun ti sọrọ naa di mimọm to si gba awọn ọmọ Naijiria niyanju pe ki wọn ṣe suuru fun iṣakooso ijọba Aarẹ Tinubu, nitori pe laipẹ jọjọ, nnkan maa too daa, tara si maa tu tẹru-tọmọ lorileede yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Latigba ti Aarẹ Tinubu ti gbajọba lati ọdun to kọja ni nnkan ti ri bakan, eyi ri bẹẹ nitori awọn ofin atawọn igbesẹ akin kọọkan to gbe nipa eto ọrọ aje ilẹ wa. Lara rẹ ni bi Aarẹ Tinubu ṣe yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu, atawọn nnkan mi-in to ṣe. Nnkan nira fawọn araalu loootọ, ṣugbọn adun lo n gbẹyin ewuro lọrọ naa maa pada jẹ nigbẹyin laipẹ rara.  O ti foju han gbangba pe nnkan ti n ṣẹnu ire laarin ilu bayii. Awọn igbesẹ akin tijọba apapọ gbe ti n so eeso rere. Ninu saa akọkọ lọdun yii, awọn onimọ ijinlẹ nipa eto ọrọ-aje orileede yii ti sọ pe nnkan ti n ṣẹnuure fawọn ọmọ orileede yii.

Iroyin ayọ ati idunu nla gbaa leyi jẹ fawọn alakooso ijọba orileede yii. Ohun kan ṣoṣo to ku ni pe kawọn eeyan ni suuru fun iṣakoso ijọba Aarẹ Tinubu, ki wọn si ni igbagbọ ninu rẹ.

Laipẹ, lai jinna rara, nnkan maa too daa, tara si maa tu awọn araalu laipẹ yii.

 

Leave a Reply