Aderounmu Kazeem
Lati fopin si rogbodiyan to n ṣẹlẹ lawọn ibi kan nilẹ Yoruba, lori bi wọn ti ṣe n jo ile, ti wọn n kọlu awọn teṣan ọlọpaa kiri, awọn aṣoju-ṣofin ti sọ pe, iru iwa bẹẹ gbọdọ dopin.
Awọn asoju-sofin kan ti wọn je ọmọ Yoruba, eyi ti Ọnarebu Fẹmi Fakẹyẹ, jẹ olori wọn, ni wọn ba awọn oniroyin sọrọ yii niluu Abuja. Ohun ti wọn si sọ ni pe ki awọn to n jo ile, ti wọn n ba dukia jẹ kiri ma sọ ilẹ Yoruba doju ogun.
Wọn ni loootọ ni gbogbo wa jẹ ọmọ orilẹ-ede yii, ṣụgbọn kaluku lo mọ ilu to ti wa, ati pe ko ni i dara ti awọn eeyan kan, paapaa awọn atọhunrinwa ba sọ ipinlẹ Eko doju ogun, ti wọn n ba dukia ijọba ati ti araalu jẹ.
Awọn aṣofin yii ti waa rọ awọn ọdọ ki wọn sinmi iwọde ti wọn n ṣe kiri niwọn igba ti ijọba ti gbohun wọn, ti igbesẹ si ti bẹrẹ lori ibeere wọn gbogbo.
O ni, ko ni i wu awọn ki ilẹ Yoruba tun la iru ohun to la kọja laye ogun wẹ-tiẹ lọdun 1964 si 65. Fun idi, ki awọn ọdọ sinmi wahala ki alaafia le pada saarin ilu.
Fakẹyẹ, tẹ siwaju pe, ki i ṣe pe awọn lodi si iwọde ifẹhonu han si ohun ti awọn ọdọ ko fẹ, ṣugbọn bi wọn ṣe n ba nnkan jẹ, ti ọpọ ẹmi n ṣofo ki i ṣe ohun ti awọn faramọ rara.
Bẹẹ gẹgẹ lawọn aṣofin yii tun bu ẹnu atẹ lu bi wọn ti ṣe kọlu Aafin Ṣoun Ogbomọṣọ, Ọba Akiolu, ati bi wọn ṣe ba dukia Aṣiwaju Bọla Tinubu, jẹ atawọn dukia mi-in to jẹ ti ijọba atawọn araalu.
O lawọn faramọ ̀ọrọ ti olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọgbẹni Fẹmi Gbajabiamila sọ wi pe eto to yẹ gbọdọ wa fun awọn ti wọn ba dukia wọn jẹ, atawọn eeyan ti wọn padanu ẹmi awọn eeyan wọn .