Awọn to lọọ ji ounjẹ korona ko atawọn to dana sun dukia yoo foju bale-ẹjọ – Ijọba Eko

Faith Adebọla, Eko

Ojilerugba o din mọkanla (229) afurasi ọdaran lọwọ awọn agbofinro ti ba fun ọkan-o-jọkan awọn ẹsun iwa ọdaran latigba tijọba ti kede ofin konilegbele nipinlẹ Eko, gbogbo wọn pata, atawọn mi-in tọwọ ba tun tẹ, nijọba loun yoo wọ de kootu lati ba wọn ṣẹjọ.

Alukoro ẹka eto idajọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Kayọde Oyekanmi, lọ sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to buwọ lu lorukọ kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ Eko. O ni niṣe lawọn janduku ẹda kan bẹrẹ si i lo anfaani iwọde tawọn ọdọ kan n ṣe ta ko awọn ọlọpaa SARS tijọba ti fofin de, lati maa ba dukia jẹ, ti wọn si n ji awọn ẹru ẹlẹru ko lọ.

Oyekanmi ni kaakiri awọn agbegbe yika ipinlẹ Eko lọwọ ti ba awọn afurasi wọnyi, ijọba si ti pari iwadii ati iwe ẹsun wọn, ati pe ninu ọsẹ yii ni wọn maa foju ba ile-ẹjọ lati wi tẹnu wọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn tọwọ ba naa ni didana sun dukia ẹlomi-in, ipaniyan, ole jija, biba dukia ijọba jẹ ati ṣiṣakọlu si awọn agbofinro. Awọn mi-in ninu awọn afurasi ọdaran yii ni wọn lọọ ko ounjẹ iranwọ COVID-19 tijọba tọju, ti wọn ja ṣọọbu awọn ẹni ẹlẹni kaakiri ipinlẹ Eko.

Ni bayii, alakooso ẹka to n gbọ ẹsun to ba kan araalu, Abilekọ Ọlayinka Adeyẹmi, ti lọ kaakiri awọn teṣan ati ọfiisi ọlọpaa tọrọ kan lati gba akọsilẹ to yẹ nipa awọn afurasi ọdaran naa ati ẹṣẹ ti wọn ṣe, lati gbaradi fun igbẹjọ ni kootu, ati pipese agbẹjọro to yẹ. O ni awọn ti n ṣa awọn to maa jẹrii ta ko awọn afurasi ọdaran jọ, gbogbo ẹri to si wa larọọwọto awọn lawọn maa tẹ pẹpẹ rẹ siwaju adajọ ni kootu.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣafihan awọn janduku kan tọwọ ba nibi ti wọn ti lọọ fọ ile itaja igbalode kan lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko, ti wọn fẹẹ ko wọn lẹru lọ. Alẹ lọwọ ba awọn yii. Lara awọn ẹru ti wọn ba lọwọ wọn tẹlifiṣan nla ẹrọ ilota oyinbo (blender), kọmputa alaagbeletan, atawọn nnkan eelo abanaṣiṣẹ mi-in. Wọn ni awọn ẹru yii ni wọn yoo ṣafihan rẹ ni kootu gẹgẹ bii ẹsibiiti ti wọn ba lọwọ wọn.

Leave a Reply