Ile-ẹjọ da ẹjọ Ṣoworẹ ati Bakare nu, wọn ni ko lẹsẹ nilẹ rara

Aderounmu Kazeem

Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan niluu Abuja ti da ẹjọ ti Ọmọyẹle Ṣoworẹ ati ẹni keji ẹ, Ọlawale Bakare, pe nu o. Ana Wẹsidee, Ọjọruu, yii ni igbẹjọ ọhun waye niluu Abuja.

Ohun ti Adajọ Stephen Adah sọ ni pe iwe ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Ṣoworẹ ati ẹni keji ẹ, Bakare, pe ko bojumu to. O ni ẹsun ọdaran ni wọn fi kan wọn, ti eeyan ba si fẹẹ pe iru ẹjọ bẹẹ, ọtọọtọ ni eeyan maa n ṣe e, ki i ṣe ọhun ti eeyan meji le pe papọ soju kan.

Yatọ si eyi, ile-ẹjọ ọhun tun sọ pe ẹni kan ṣoṣo lo fọwọ si iwe ipejọ naa, bo tilẹ jẹ pe ohun ti wọn n sọ ni pe iwe ipejọ eeyan meji ni.

Wọn ni fun idi eyi, ẹjọ ti Ọlawale Bakare ati Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ẹni to dije dupo aarẹ orilẹ-ede yii pẹlu Muhammed Buhari, pe ko lẹsẹ nilẹ rara.

Tẹ o ba gbagbe, ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja ni wọn ti n ba Bakare ati Ọmọyẹle Ṣoworẹ ṣẹjọ, ẹsun ti wọn si fi kan wọn ni i ṣe pelu iditẹ-gbajọba, atawọn ẹsun mi-in bii jibiti, lilo ẹrọ ayelujara fi dunkooko, bẹẹ ni wọn tun fẹsun kan wọn wi pe wọn n bu Aarẹ Muhammed Buhari.

Bọrọ ọhun ṣe wa niyẹn ki Adajọ Ijeoma Ojukwu too fun wọn ni beeli lọjọ kẹrin oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Lara ofin ti wọn si fi de wọn ni pe Ṣoworẹ ko gbọdọ ba wọn duro sibi ipejọ kankan ko sọ pe oun fẹẹ ba araalu sọrọ. Bakan naa ni wọn tun fofin de e wi pe ko gbọdọ kuro niluu Abuja, nigba ti wọn sọ pe Bakare ni tiẹ ko gbọdọ kọja ipinlẹ Ọṣun to  n gbe.

Awọn ofin ti wọn fun awọn eeyan mejeeji niyẹn, ohun tawọn naa si ṣe ni pe wọn lawọn yoo pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori ẹ. Ẹjọ ti wọn pe naani wọn ti danu yii o.

Leave a Reply