Adajọ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun Ọlanrewaju ati Kazeem ti wọn jale l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti to fikalẹ siluu Ado-Ekiti, ti dajọ iku fawọn meji kan, Ọkẹ Ọlanrewaju ati Ọlanbiwọnnu Kazeem, lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati idigunjale.

Onidaajọ Lekan Ogunmoye lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Akọsilẹ kootu naa ṣalaye pe ogunjọ, oṣu keje, ọdun 2016, ni Ọkẹ to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji ati Ọlambiwọnnu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, huwa ọhun nile kan to wa laduugbo Ameen, ni Federal Housing Estate, to wa l’Oke-Ila, niluu Ado-Ekiti, pẹlu bi wọn ṣe kọ lu Alhaji Ameen Rasheed, ti wọn si digun ja a lole, bẹẹ ni wọn gba awọn foonu rẹ.

Bakan naa ni wọn tun kọ lu Ọlaoti Abiọdun, ẹni ti wọn gba owo ati foonu ẹ.

Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ, adari ẹka to n ṣegbẹjọ araalu (DPP), Julius Ajibare,  pe ẹlẹrii mẹta, nigba ti Amofin Chris Omokhafe to ṣoju olujẹjọ pe ẹlẹrii mẹrin.

Onidaajọ Ogunmoye ni awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn eeyan naa digun jale. O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn, bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun ṣaanu fun ẹmi wọn.

Leave a Reply