Awọn mẹfa to ji ibeji Akewugbagold gbe ṣi wa lọgba ẹwọn n’Ibadan

Aderounmu Kazeem

Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Ibadan, ti sọ pe ọsẹ to n bọ yii loun yoo ṣo ero oun lori beeli ti agbẹjọro awọn ọkunrin mẹfa kan ti wọn ji ọmọ Aafaa oniwaasi nni, Alhaji Taofeek Akewugbagold, gbe niluu Ibadan.

Orukọ awọn mẹfẹẹfa ọhun ni; Muhammed Bashir, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn; Fatai Akanji; Oyelẹyẹ Ọpẹyẹmi, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn; Ọlamide Ajala, ẹni ọdun mẹrindinlogoji; Rafiu Mutiu, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati Taiwo Ridwan, ẹni ọgbọn ọdun.

Ẹsun onikoko mẹta ni wọn  ka si wọn lẹsẹ, wọn ni wọn gbimọ pọ lati ji ni gbe, ati pe wọn ji awọn ibeji Akewugbagold gbe, ti wọn si tun ba awọn ohun ọṣẹ oloro lọwọ wọn.

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹrin ọdun yii ni wọn ji awọn ibeji ọhun gbe laduugbo Ṣaṣa n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ. Miliọnu mẹrin naira ni wọn sọ pe Akewugbagold san, ki wọn too da awọn ọmọ ọhun pada fun un.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ keje, oṣu kẹsan-an ọdun yii ni wọn ti kọkọ ko wọn wa sile ẹjọ majisireeti kan ni Iyaganku, n’Ibadan, ki adajọ too sọ pe ile-ẹjọ giga ni yoo gbọ ọrọ ọhun.

Lojuẹsẹ naa lo ti ni ki wọn lọọ ko awọn gende mẹfa ọhun si ọgba ẹwọn naa, titi ti igbẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ nile- ẹjọ giga.

Mọnde, ọsẹ yii, ti ẹjọ ọhun tun waye ni Olupẹjọ, Arabinrin Margaret Ojo, sọ pe ọjọ yẹn lo yẹ ki igbẹjọ wọn waye, ṣugbọn wọn ko ko awọn ẹni-afurasi naa wa sile-ẹjọ.

Nibẹ naa lawọn agbẹjọro wọn ti fi ye adajọ wi pe awọn ti bẹbẹ fun beeli wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn ko si ni kootu lọjọ naa.

Agbẹjọro wọn, Uwawah Oritshuwa, sọ ọ nile-ẹjọ wi pe lọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa ati ọjọ kẹsan-an oṣu kọkanla yii loun ti gbe igbesẹ lori ẹbẹ fun beeli wọn.

Ṣa o, Olupẹjọ, ti bẹ ile-ẹjọ ko sun igbẹjọ siwaju ki oun le ni anfaani lati fesi si ẹbẹ fun beeli ti awọn agbẹjọro awọn eeyan ti wọn  fẹsun kan yii n beere fun.

Ọjọ kejidinlogun oṣu yii, iyẹn ọsẹ to n bọ ni Adajọ, Mashud Abass, sọ pe oun yoo gbọ ẹjọ wọn, paapaa lori beeli ti awọn agbẹjọro wọn n bẹbẹ fun.

Leave a Reply