Faith Adebọla, Eko
Temutemu ni ahamọ ọlọpaa ipinlẹ Eko kun lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, pẹlu bọwọ awọn agbofinro naa ṣe tẹ okoolelẹẹẹdẹgbẹrin (720) afurasi ọdaran kaakiri ipinlẹ naa, pẹlu awọn nnkan ija ati egboogi oloro ti wọn ka mọ wọn lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọbi, lo kede ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE, o ni lati nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Aiku yii lawọn agbofinro ti bẹ jade si awọn ibuba ti wọn ti sami si pe awọn ọmọ ganfe atawọn janduku fi n ṣe ibugbe wọn.
Adejọbi ni iṣẹ apawọpọ ṣe lawọn fi kinni ọhun ṣe, tori kaakiri ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mẹrẹẹrinla to wa lawọn ijọba ibilẹ gbogbo nipinlẹ Eko lawọn ti ṣiṣẹ naa, awọn o si fu ẹnikẹni lara, bẹẹ lawọn ko ṣe e lalariwo.
Ibuba mọkandinlogoji ọtọọtọ lawọn ọlọpaa naa lọọ gbọn yẹbẹyẹbẹ, ibẹ si lọwọ ti ba awọn afurasi ti wọn fi pampẹ ofin gbe naa.
Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ibọn ilewọ oyinbo ati ibọn ṣakabula, ọta ibọn rẹpẹtẹ, oogun abẹnu-gọngọ loriṣiiriṣii, egboogi oloro ti wọn fura si pe igbo ati kokeeni ni wọn, ada, ọbẹ, aake atawọn nnkan ija mi-in. Gbogbo ẹ lawọn ọlọpaa naa ko gẹgẹ bii ẹri ta ko awọn afurasi ọhun.
Ọpọ dukia ati ẹru ẹlẹru mi-in bii jẹnẹretọ tuntun meji, ẹrọ amuletutu, awọn baagi, batiri mọto tuntun atawọn ẹru mi-in ni wọn ba lakata awọn afurasi naa. Wọn ni wọn jẹwọ pe awọn kọ lawọn ni in, asiko rogbodiyan iwọde SARS lẹru naa de ọdọ awọn.
Gẹgẹ bi Adejọbi ṣe wi, o lawọn fura pe awọn janduku tọwọ ba naa lo wa lẹyin bi wọn ṣe lọọ fọ awọn ṣọọbu itaja nla nla kan l’Ekoo lasiko iwọde ta ko SARS to waye loṣu to kọja.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti gboriyin fawọn agbofinro fun bi wọn ṣe ṣiṣẹ naa bii iṣẹ, o ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati le jẹ ki aabo to peye wa nipinlẹ Eko, kawọn araalu si sun oorun a-sun-fa-lala.
Ni bayii, Odumosu ni iṣẹ iwadii gbọdọ bẹrẹ loju ẹsẹ, kawọn afurasi naa le foju bale-ẹjọ laipẹ. O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, awọn o ni i sinmi titi ti iwa ipanle ati janduku yoo fi kasẹ nilẹ l’Ekoo, paapaa pẹlu bi asiko pọpọṣinṣin ọdun ṣe n kanlẹkun yii.