Ọwọ tẹ meji ninu awọn to sun ọlọpaa jẹ lasiko SARS n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọsẹ mẹta ti awọn ọmọ iṣọta ti dana sun ọlọpaa meji laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, ti wọn si pin ẹran ara wọn jẹ bii ẹni jẹ suya laarin ara wọn, ọwọ awọn agbofinfro ti tẹ meji ninu awọn eeyan naa.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun’) oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, lawọn ọmọ iṣọta dana sun awọn Sajẹnti ọlọpaa meji kan,  Ajibọla Adegoke ati Rotimi Ọladele, lasiko ti wọn n lọ sẹnu iṣẹ, wọn ni wọn fi mọto gba ọlọkada kan, iyẹn si ṣe bẹẹ jade laye.

Eyi lo mu ki awọn ọdọ to n ṣewọde ta ko ẹka (SARS) lasiko naa le awọn ọlọpaa mẹta naa ba, ṣugbọn to jẹ pe ẹkẹta wọn to n jẹ Ọṣọ Ojo nikan lori ko yọ. Ipo Ripẹtọ loun wa lẹnu iṣẹ ọlọpaa ni tiẹ. Ikọ awọn agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst lo doola ẹmi ẹ pẹlu bi wọn ṣe gbe e sinu mọto wọn, ti wọn si gbe e sa kuro lagbegbe naa.

Obinrin alaboyun kan, Oluwakẹmi Aṣabi, ti ko ju ẹni ọdun mẹrinlelogbọn (34) lọ pẹlu ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji (32) kan to n jẹ Saheed Ọlalekan Oyebade lawọn agbofinro ri mu pe wọn lọwọ ninu iwa ọdaran naa.

Kayeefi to wa nibẹ ni pe lẹyin ti wọn dana sun awọn ọlọpaa naa bii ẹran ọdun Ileya tan, eyi obinrin inu wọn ni wọn lo gba nnkan ọmọkunrin ọkan ninu wọn, to si lọọ jẹ koro mejeeji to wa ninu e bii ẹni jẹ kíndìnrín ẹran.

Oluwakẹmi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Ìyá Ọba pẹlu Saheed atawọn ti wọn pin ẹran awọn agbofinro naa jẹ la gbọ pe wọn gbe igbesẹ ọhun lati fi i ṣe aajo owo.

Obinrin oloyun to ti bimọ meji sẹyin yii lọwọ awọn atọpinpin ọlọpaa kọkọ ba lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun yii, lẹyin ti fidio kan to tan kaakiri ori ẹyọ ayelujara ti ṣafihan ẹ ketekete.

Afurasi ọdaran yii jẹwọ pe loootọ loun wa nibẹ lasiko ti wọn dana sun awọn ọlọpaa naa, ti awọn eeyan si pin ẹran wọn mọwọ, ṣugbọn oun ko ba wọn jẹ nibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mi o si lara awọn to pa ọlọpaa yẹn. Ọgbẹni Saheed lo fun mi ni nnkan ọmọkunrin ọkan ninu wọn, wọn ni ọmọ mi, iwọ naa lọọ fi mu ẹkọ, ṣugbọn mo kan gba a ni, mi o jẹ ẹ, mo kan mu un lọ sile lati fi han awọn eeyan mi ni. Bo si ṣe dalẹ ni wọn ti waa gba a pada lọwọ mi.”

Ọrọ to sọ yii lo jẹ ki awọn ọlọpaa lọọ mu Saheed, ti ọkunrin to pera ẹ lọmọ ẹgbẹ awakọ n’Ibadan yii si fidi ẹ mulẹ pe oun loun fun Oluwakẹmi lẹran eeyan naa, to si jẹ ẹ, ati pe oun ko gba a pada lọwọ obinrin naa gẹgẹ bii awijare ẹ fawọn agbofinro.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi iroyin yii mulẹ, o ni wọn ti gbe awọn afurasi ọdaran yii lọ si ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran lolu ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii niluu Abuja.

 

Leave a Reply