O yẹ kinu ọmọ Naijiria maa dun pe ijọba fẹẹ maa ra epo bẹntiroolu lati orileede Nijee- Sylva

Faith Adebọla, Eko

 “Emi o ri nnkan itiju kankan ninu iyẹn o. Ko tiẹ si nnkan to buru nibẹ rara. Orileede to tobi ni Naijiria, a si nilo epo rẹpẹtẹ. Koda, bi awọn ibudo ifọpo wa ba tiẹ n ṣiṣẹ paapaa, a ṣi nilo lati ra epo si i, ka le ni anito ati aniṣẹku. Niṣe lo yẹ ka gboriyin fun ijọba apapọ bi wọn ṣe fẹẹ bẹrẹ eto lati maa ra epo bẹntiroolu wọlu lati orileede Nijee (Niger), ko si abuku kan ninu ẹ rara.”

Minisita fun ọrọ epo rọbi, to tun jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ ri, Timipre Sylva, lo ṣe bayii sọrọ nipa igbesẹ tijọba apapọ lawọn fẹẹ gbe lati maa ko epo wọle lati orileede alaamulegbe wa, Niger Republic. Ori eto tẹlifiṣan Channels kan lo ti sọrọ naa lalẹ ọjọ Aje, Mọnde yii.

Sylva ni dipo ti awọn eeyan fi n tẹmbẹlu igbesẹ tijọba fẹẹ gbe naa, ti wọn n wo o bii nnkan itiju fun Naijiria, niṣe lo yẹ ki wọn ri i bi anfaani lati mu ki ajọṣe olokoowo ati ọrọ-aje laarin orileede Iwọ-Oorun Afrika kan si omi-in tubọ fidi mulẹ daadaa si i.

O ni ko sọgbọn ti orileede wa le da si i lọwọ yii, tori epo ta a nilo lojumọ kan pọ ju ohun ti agbara wa le ka lati pese labẹle lọ.

Ṣe l’Ọjọruu, Tọsidee, to kọja yii, ni ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ epo rọbi fi iwe kan lede pe ajọsọ ati adehun ti duro laarin orileede wa ati Nijee lati maa ra epo rọbi wa silẹ wa. Ileeṣẹ ifọpo Soraz Refinery, to wa ni Zinder, lorileede Nijee, ni wọn ti fẹẹ maa ra epo bẹntiroolu naa wọle.

Igbesẹ yii ti da awuyewuye pupọ silẹ, pẹlu bawọn eeyan ṣe n bẹnu atẹ lu ijọba apapọ pe igbesẹ ainitiju ni, wọn ni ko sohun to yẹ ko mu awọn ibudo ifọpo nla nla ta a ni lati ma ṣiṣẹ. Ọrọ ọhun si ṣi n ja ranyin di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply