Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ikorodu kọju ija si t’Odogbolu, lawọn ọlọpaa ba ko wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Mẹrin ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da Ikorodu,  niluu Eko laamu lawọn ọlọpaa mu l’Odogbolu, nipinlẹ Ogun lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla to pari yii, lasiko ti wọn waa ja nitori ibọn ilewọ ti wọn yoo fi máa ṣọṣẹ. Wọn si mu awọn meji ti wọn jẹ ọmọ Odogbolu pẹlu.
Àwọn tọwọ ba naa ni: Aboyeji Oluwadamilare,  Adebiyi Matthew,  Jacob Solomon ati Iliasu Jubril. Àwọn meji yooku tawọn jẹ ọmọ Odogbolu ni Olubanjọ Ṣẹgun lati Iselu Odogbolu ati Samuel Ọlaniyan toun naa wa lati Iselu kan naa.
Ohun to ṣẹlẹ gan -an gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe alukoro ọlọpaa nipinlẹ yii ṣe wi ni pe, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ikorodu bẹ Samuel lọwẹ l’Odogbolu lati ba awọn ra ibọn ilewọ ibilẹ kan.
O ra ibọn ọhun o si fi ranṣẹ, ṣugbọn nigba tawọn t’Ekoo fẹẹ lo o ni wọn ri i pe ibọn naa ko daa, ko ṣee lo rara. Ohun to bi wọn ninu ree,
ni wọn ba ni awọn ọmọ ẹgbẹ Odogbolu yii ti gbabọde ni.
Ibinu yii lo mu wọn gbeja waa ba awọn meji to wa l’Odogbolu, ni wọn ba sọ wahala gidí kalẹ lọjọ Ẹti to kọja yii, lati da sẹria fun Samuel ati Ṣegun.
Nibi ti wọn ti n fa wahala ọhun ni olobo ti ta awọn ọlọpaa Odogbolu, bi wọn ṣe waa ko wọn niyẹn. Ibọn ilewọ ibilẹ kan ati ọta ibọn ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

Leave a Reply