Nitori gbese  owo-osu, awọn oṣiṣẹ fasiti ipinlẹ Ondo fẹẹ bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ mẹrinla

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti ti ki i ṣe olukọ, ẹka tipinlẹ Ondo ti pasẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn lati bẹrẹ iyansẹlodi ọlọsẹ meji lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii lori bi ijọba ṣe kuna lati san ọpọlọpọ owo-osu ti wọn jẹ wọn.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade ti wọn fi sita lati ọwọ Ọgbẹni Aguda Temitọpẹ ti Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko, pe dandan ni fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ awọn to n siṣẹ lawọn fasiti mẹtẹẹta to wa nipinlẹ Ondo lati tẹle asẹ iyansẹlodi naa.

O ni ko sẹni to gbọdọ yọju sibi isẹ fun ohunkohun laarin asiko naa, yatọ sawọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ oṣiṣẹ alaabo.

Aguda ni asiko ti to fun awọn oṣiṣẹ lati gba ara wọn silẹ, o ni awọn ko ni i laju silẹ maa woran kijọba sọ awọn di onibaara ọsan gangan.

Leave a Reply