Wọn rọ Onírọ̀ ti ilu Irọ̀, l’Ọbafẹmi Owode, loye

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati ọdun 2014 ni ẹjọ ti wa ni kootu lori ipo ọba Ọnirọ ti Ilẹ Irọ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode, nipinlẹ Ogun, eyi ti Ọba Najeemdeen Alani Aromaye, di mu, ti wọn ni ki kabiyesi naa yee pe ara ẹ lọba, ṣugbọn ti ko gbọ, to jẹ niṣe lo n ṣajọyọ ipo ọba.

Ni bayii, ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye jijẹ nipinle Ogun ti dide si ọrọ naa, wọn si ti paṣẹ pe Aromaye ko gbọdọ gba owo-oṣu lọwọ ijọba mọ, bẹẹ si ni ko gbọdọ pe ara ẹ lọba Irọ mọ titi ti kootu yoo fi da ẹjọ rẹ sibi kan.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹrin, oṣu kejila yii, ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun, kọ lẹta si ajọ lọbalọba ipinlẹ yii, (Egba Traditional Council) lati dawọ owo sisan duro fun Onirọ, lẹta naa ṣẹṣẹ jade sọwọ awọn akọroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa yii, ni.

ALAROYE pe kọmiṣanna fun ileeṣẹ yii, Afọlabi Afuwapẹ, lati fidi aṣẹ naa mulẹ. Afuwapẹ sọ pe ootọ ni, aṣẹ kootu wa nilẹ pe Najeemdeen ko gbọdọ pe ara ẹ lọba Onirọ, ko si gbọ, iyẹn lo fa a ti aṣẹ tun fi wa lọtẹ yii pe wọn ko gbọdọ sanwo fun un mọ, oun naa ko si gbọdọ pe ara ẹ lọba mọ titi digba ti kootu yoo fi dajọ, ṣugbọn ki wọn maa tọju owo-oṣu rẹ naa pamọ si asunwọn kan naa.

Ohun to kọkọ bi wahala fun ọba yii ni pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2014, lo ṣeto iwuye, to si di ọba. Bẹẹ, ọjọ keji ti kootu paṣẹ pe ko gbọdọ dabaa igbesẹ ọba jijẹ naa ree, eyi ti ile-ejọ sọ pe o tumọ si itapa si aṣẹ ijọba.

Adajọ  Gboyega Ogunfowora lo da ẹjọ naa lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2014, ṣugbọn ọjọ keji rẹ ni Aromaye sọ ara rẹ dọba, bẹẹ lo si n ṣayẹyẹ bo ṣe wa lori ipo naa pẹlu.

Ọdun 2016 ni kootu tun ṣiwee kan an, ti wọn ni ọkunrin naa jẹbi pipe ara rẹ lọba pẹlu bo ṣe ta ko aṣẹ kootu.

Ṣugbọn ọba naa pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun n’Ibadan, wọn si fun un laaye lati wa nipo naa. Ṣugbọn ni bayii, ohun to kọja ko-tẹ-mi-lọrun ti ṣẹlẹ lori ẹjọ ọhun, nitori ileeṣẹ ọrọ oye jijẹ ṣalaye ninu lẹta wọn pe wọn ti fagi le anfaani ti wọn fun Aromaye lati maa jọba lọ, kootu si ti da ẹbẹ naa nu.

Walaha ko deede ṣẹlẹ lori ipo ọba yii, awọn idile Ọlẹyọ tawọn naa jẹ ọmọ oye ni wọn ni Najeemdeen ko lẹtọọ si ipo naa, ti wọn ni awọn yoo jọ fi ofin fa ọrọ ọba yii ti yoo fi ja sibi to yẹ ni.

Leave a Reply