Ko pẹ ti Rauf gba igbega lẹnu iṣẹ ọlọpaa ni wọn ni awọn ọtẹlẹmuyẹ pa a l’Osogbo

Florence Babaṣọla

Ko sẹni to le de agbegbe ọja Olobu, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti awọn mọlẹbi ọmọkunrin ọlọpaa kan, Kọpura Fawale Rauf, to ti doloogbe bayii n gbe, ti ko ni i kaaanu abiamọ.

Ṣe ti ọmọ ikoko ti ko ti i pe oṣu kan ti iyawo oloogbe naa n gbe dani ni, abi ti awọn obi rẹ ti wọn n wa ẹkun mu bii omi? Ṣe ti awọn aburo Rauf ti wọn n pariwo pe ogo idile awọn lo ti lọ ni, abi ti awọn araadugbo ti wọn n royin iwa tutu ati suuru rẹ?

Bawo lọrọ ṣe jẹ gan an? Ọdun 2016 ni Rauf darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa lẹyin to jade ileewe, inu oṣu kin-in-ni ti a wa yii lo si gba lẹta igbega si ipo kọbura lẹnu iṣẹ. Agọ ọlọpaa to wa ni Dada Estate, niluu Oṣogbo, lo ti n ṣiṣẹ ko too pade iku ojiji lọjọ kẹrinla, oṣu ti a wa yii.

Gẹgẹ bi iyawo oloogbe, Fawale Balikis, ṣe sọ fun ALAROYE, “Ibiiṣẹ lo dagbere laaarọ ọjọ naa, nigba to si di alẹ ti n ko gburoo rẹ, mo ni boya o n ṣiṣẹ alẹ (night shift) ni. Foonu mi si ti ku, n ko raaye pe foonu rẹ.

“Nigba to di aarọ ọjọ keji, mo gburoo ọkada kan niwaju ile, ẹnikan ti a n pe ni Bọọda Tunji ni wọn gbe ọkọ mi wale, o si rin wọnu ile lai sọrọ. Mo beere pe ki lo ṣẹlẹ, ṣugbọn ko da mi lohun, mo kọju si ẹni to gbe e wa pe ki lo ṣe ọkọ mi, iyẹn naa ko fun mi lesi, ṣe lo kan sọ pe ki ọkọ mi sinmi daadaa, ko si maa lo oogun rẹ, igba yẹn lo ko awọn oogun kan fun un pẹlu risiiti ileewosan LAUTECH.

“Bi wọn ṣe lọ tan lọkọ mi sun sori bẹẹdi, ko sọrọ kankan, mo waa ro pe boya oogun tabi abẹrẹ ti wọn fun un lo mu ko rẹ ẹ ni. Ṣugbọn titi ti ilẹ fi ṣu, ko laju, bẹẹ ni ko sọrọ. Bi ilẹ ọjọ keji, ṣe mọ ni mo pe aburo ọkọ mi obinrin tawọn naa n gbe Ilobu pe bi ọkọ mi ṣe n ṣe ko ye mi.

“Nigba ti ẹni yẹn de ni wọn fi agbara yi ẹgbẹ ọkọ mi pada lori bẹẹdi to sun si, bẹẹ la ri i pe ẹjẹ ti di sinu eti ẹ, oju-apa kekere kan si wa lẹyin ori rẹ. Aburo ọkọ mi sọ pe ka maa gbe e lọ si ọsibitu, a gbe e lọ si ọsibitu Aanu-Olu, lẹyin ayẹwo ni wọn dari wa sileewosan LAUTECH.

“Ni LAUTECH, wọn ni ka lọọ ya aworan agbari ẹ, inu aworan yii la ti ri i pe ori yẹn ti san sinu, ẹjẹ ti rọ sibi ti ko yẹ ko rọ si, oriṣiiriṣii apa lo ti wa ninu agbari yẹn. Bayii ni wọn dari wa si UCH, Ibadan, ẹnikan lo wa sọ fun wa pe dokita kan wa lagbegbe Oke-fia toun naa kọṣẹ-mọṣẹ nipa iṣẹ-abẹ ori.

“Bi a ṣe debẹ, dokita yẹn sọ pe oun le ṣe iṣẹ naa, ṣugbọn alẹ lawọn maa n ṣeru ẹ. O ni ka lọọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira na (#500,000). A wa owo kaakiri, wọn si ṣe iṣẹ-abẹ naa lalẹ Satide yii kan naa, sibẹ ọkọ mi ko sọrọ.

“Odidi ọsẹ kan la lo nibẹ, ẹrọ tawọn alaaarẹ fi maa n mi (oxygen) ni wọn gbe si i lẹnu, ṣugbọn nigba to di alẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ọkọ mi jade laye, a si sin in nilana ẹsin Islam.

“Ninu iwadii ti a ṣe lori ohun to ṣẹlẹ si ọkọ mi lo ti di mimọ pe nigba to ṣiwọ lẹnu iṣẹ lalẹ ọjọ kẹrinla, yẹn ni ọga rẹ kan, Mọdi, pe e sibi ayẹyẹ ọjọọbi to fẹẹ ṣe nileetura River Side, niluu Oṣogbo. Ibi ayẹyẹ naa la gbọ pe wọn wa tawọn ọtẹlẹmuyẹ DSS mẹta kan fi doju ija kọ ọ.

“A gbọ pe ọkan lara wọn, David Olowopọrọku, lo kọkọ jan irin mọ ọn lori, ki awọn meji ti wọn jọ wa nibẹ too bẹrẹ si i jan nnkan mọ ọn, koda, ọwọ to gbe soke lati da irin yẹn duro rọ (paralyse) loju-ẹsẹ, to si wa bẹẹ titi ti a fi sinku rẹ. Titi di asiko yii, a ko rẹni sọ fun wa ohun to pa oun atawọn DSS ọhun pọ to fi di pe wọn lu u pa.

‘Mo n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ọṣun ati kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ yii pe ki wọn ṣaanu mi, ki wọn ma jẹ ki iya yii jẹ mi gbe, ọmọ mẹta ni mo ti bi fun un, ọmọ ọdun mẹjọ lakọbi wa. Ki wọn ma jẹ kawọn DSS yii fọwọ ọla gba mi loju, mi o lẹnikan, ki wọn ba mi wa awọn to wa pẹlu David Olowopọrọku lọjọ naa ri, ki awọn mẹtẹẹta naa le foju winna ofin”

Bakan naa lọrọ ri lẹnu baba to bi Rauf, Alagba Fawale Rabiu. Baba yii ni oloogbe lakọbi ninu awọn ọmọ toun bi, o ni wọn ti kan oun leyin ọọkan pẹlu bi wọn ṣe pa ọmọdekunrin ẹni ọdun marunlelọgbọn naa, ṣugbọn oun nigbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn aa ṣawari awọn DSS mẹtẹẹta ti wọn fina ọmọ jo oun.

ALAROYE de ọdọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, o ni loootọ lawọn ti gbọ nipa iku ọmọkunrin naa, ati pe ileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ Ọṣun ti mu Olowopọrọku atawọn meji ti wọn fẹsun ọhun kan, bẹẹ ni wọn si ti n ṣewadii wọn lọwọ.

O ni Kọmisanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa rara, o si ti beere fun pe ki awọn ọtẹlẹmuyẹ taari awọn mẹtẹẹta sọdọ awọn ọlọpaa fun iwadii to jinlẹ lori iṣẹlẹ naa lati le mọ nnkan to da wọn pọ lọjọ yii, bẹẹ lo ti fi to olu ileeṣẹ ọlọpaa leti l’Abuja.

Ọpalọla ke si awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo to ku lati ri ara wọn bii ọmọ iya, ki wọn mọ pe erongba aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lawọn jọ n ṣiṣẹ tọ. O tun ke si awọn araalu lati ma ṣe jẹ ki iṣẹlẹ naa dẹruba wọn, nitori yoo yanju laipẹ, iru rẹ ko si tun ni ṣẹlẹ mọ.

Leave a Reply