Baba awọn tẹgbọn-taburo ti wọn pa sinu igbo l’Oṣogbo ṣalaye bọrọ naa ṣe ṣẹlẹ f’ALAROYE

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Baba ọkan lara awọn ọmọ to ku lasiko ti akẹkọọ kan, Muyideen Usman, pẹlu Fulani darandaran, Isa Memudu, ji wọn gbe pamọ sinu igbo niluu Oṣogbo lọsẹ to kọja, Diakoni Thompson Adewale Onibokun, ti sọ pe Muideen ki oun lọjọ ti wọn fẹẹ ṣiṣẹ ibi ọhun, ṣugbọn oun ko fura pe o le huwa buburu naa.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun ALAROYE, “Orukọ mi ni Diakoni Thompson Adewale Onibokun, emi ni baba awọn ọmọ mejeeji, ọmọọmọ mi ni eyi to jẹ ọmọ ọdun mejila, ọmọ mi obinrin lo bi i, nigba ti eyi to jẹ ọmọ ọdun mẹtala jẹ abigbẹyin mi.

“Lọjọ Mọnde tiṣẹlẹ yẹn ṣẹlẹ, mo n lọ si ṣọọsi ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ. Ṣọọsi wa ko jinna sile ti a n gbe rara lagbegbe Iludun, mo fi awọn ọmọ mejeeji sinu ile, wọn ti de lati ileewe, ileewe wọn ko si jinna sile wa, mo sọ pe ki wọn ṣe awọn iṣẹ kan silẹ fun mi ninu ile.

“Bi mo ṣe kuro ni ṣọọsi ni aago mẹfa kọja iṣẹju diẹ, tori wakati kan pere ni eto ti a ṣe ni sọọṣi lọjọ naa, ni ipe kan wọ ori foonu mi, wọn fi nọmba yẹn pamọ, emi o ki i gbe ipe ti nọmba ko ba si nibẹ nitori iṣẹ mi, oniṣowo ni mi, ṣugbọn mo gbe ipe yẹn.

“Nigba ti mo beere pe ta lo n ba mi sọrọ, o ni ki n dakẹ ẹnu mi, o ni ṣe emi ni Ọgbẹni Onibokun, mo ni bẹẹni, o ni awọn ti ji ọmọ mi ati ọmọọmọ mi gbe, alaafia si ni wọn wa, ṣugbọn ti mo ba fẹẹ ri wọn laaye, ki n wa miliọnu lọna mẹẹẹdọgbọn naira jade laarin ọjọ meje, loju-ẹsẹ ni mo da wọn lohun pe Ọlọrun ju gbogbo eeyan lọ laye, o si pa foonu mọ mi lẹnu.

“Mo denu ile lati mọ boya awọn ọmọ mi wa ninu ile, mo ba iya wọn nibi to ti n wa wọn kaakiri, mo beere pe ibo ni wọn le wa ko ma baa fura, o ni boya wọn ṣere lọ sọdọ awọn ọrẹ wọn ni.

“Mo sa jade ninu ile, mo fori le ọdọ pasitọ wa lati ṣalaye oun to ṣẹlẹ fun wọn, mo pe DPO kan to ti fẹyinti ni Ọta-Ẹfun, o ni ki n ni ṣuuru, mo pe eeyan mi kan to jẹ ACP l’Abuja, o bẹrẹ si i ba kọmiṣanna ọlọpaa Ọṣun sọrọ.

“Lọjọ Tusidee, mo wa si agọ ọlọpaa ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ kọja, awọn ọmọkunrin yẹn pe mi pada pe mo ti lọọ sọ nnkan to ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa, mo ni rara, mo ni ki wọn jọwọ, ran mi lọwọ, ko sibi ti mo ti fẹẹ ri owo yẹn tori oṣiṣẹ-fẹyinti ni mi lati ọdun mẹjọ sẹyin, oore-ọfẹ Ọlọrun la fi n gbe.

“Nigba to tun ṣe diẹ, wọn pe pada pe awọn ko ba mi ṣere rara, wọn ni miliọnu lọna mẹẹẹdọgbọn naira yẹn ni ki n tete wa, awọn yoo si sọ ibi ti ma a gbe e si ti ọjọ ba ti pe.

“Latigba yẹn lawọn ọlọpaa ti n ṣiṣẹ nla lati mọ ibi ti ipe yẹn ti n wa, wọn gbiyanju pupọ, aṣiri Muyideen to mu foonu yẹn lọwọ si tu. Nigba ti wọn mu awọn ọlọpaa debi ti awọn ọmọ mi wa, wọn ti ku.

“Muyideen jẹ aburo ọkọ ọmọ mi obinrin to bi ọkan lara awọn ọmọ yẹn, ṣugbọn ki i ṣe ẹgbọn Muideen lọmọ mi bi ọmọ yẹn fun.

“Koda, mo ri i lọjọ ti wọn ṣiṣẹ ibi yẹn, ṣugbọn ṣe ni mo ro pe bo kan ṣe maa n waa bẹ wa wo ni. Latọjọ Mọnde yẹn ni n ko ti ri i mọ titi di aarọ yii ti mo ri i lọdọ awọn ọlọpaa. N ko gbagbọ rara tori n ko fura si i, ko ṣẹṣẹ maa ba awọn ọmọ yẹn ṣere lai mọ pe o ti ni ero buburu lọkan tẹlẹ”

Leave a Reply