Ijamba ina ba dukia olowo nla jẹ niluu Bode Saadu

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

O kere tan, ṣọọbu mẹsan-an pẹlu awọn ọja olowo nla to wa ninu ẹ lo jona raurau lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ninu ọja Bode Saadu, lọna Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

Ina ọhun la gbọ pe o ṣẹ yọ ni nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun Lord.

Alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye pe Musbaudeen lo ta ileeṣẹ awọn lolobo nipa iṣẹlẹ naa lori foonu.

 

 

O ni laarin aadọta ṣọọbu to wa ninu ọja naa, mẹsan-an ni ina naa jo. O ṣalaye pe akitiyan awọn oṣiṣẹ awọn lati tete pa ina naa ni ko jẹ ki kinni ọhun burẹkẹ ju bẹẹ lọ.

O rọ araalu lati maa kiyesara, ki wọn si ṣọra fun ohun to le fa ijamba ina lasiko ọgbẹlẹ yii.

Leave a Reply