Ko sohun to buru ninu ki Fulani maa gbebọn AK 47 kiri lati fi daabo bo ara wọn- Bala

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed, ti sọ pe ko si ohun to buru ninu bi awọn Fulani darandaran ṣe n gbe ibọn kiri lati fi daabo bo ara wọn lọwọ awọn to n ji wọn ni ẹran gbe.

Nibi ayẹyẹ ọsẹ awọn oniroyin ti wọn pe e si ni gomina yii ti sọrọ ọhun. Nibẹ naa lo ti bu ẹnu atẹ lu ọwọ ti awọn gomina kan fi mu ọrọ awọn Fulani darandaran ti wọn ni ki wọn kuro nipinlẹ awọn bayii.

Bala Mohammed sọ pe nitori ti awọn eeyan kan maa n ji maaluu gbe lẹyin awọn Fulani lo jẹ ki wọn maa gbe ibọn AK 47 kiri lati fi koju awọn ajẹrangbe to n da wọn laamu, ati pe ko si ohun to buru ninu ki eeyan daabo dukia ti o n pawo wọle fun un.

Ṣiwaju si i, o ni ohun to buru ni bi awọn gomina kan nilẹ Yoruba ṣe dẹyẹ sawọn Fulani, paapaa Gomina Rotimi Akeredolu, to loun fun wọn lọjọ meje ki wọn fi ko aasa wọ kuro nipinlẹ Ondo.

O ni ohun ti gomina ọhun ṣe ko bojumu to nitori ọmọ Naijiria lawọn Fulani naa, bẹẹ ni wọn lẹtọọ lati maa ṣowo wọn nibi yoowu ti wọn ba fẹ ni Naijria.

Gomina ipinlẹ Bauchi yii sọ pe lati bii aadọjọ ọdun sẹyin lawọn Yoruba kan ti ṣe ọrọ aje wa si ilẹ Hausa, ti wọn ko si kuro ni agbegbe awọn doni. O ni eyi to tiẹ waa dun oun ju ni ti Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, to jẹ pe oun gan-an lo ṣiwaju awọn gomina to n pariwo pe awọn ko fẹ Fulani mọ lawọn ipinlẹ awọn.

Ọkunrin Hausa yii waa pari ọrọ ẹ pe ko sohun to buru ninu bi wọn ṣe n gbe ibọn kiri, paapaa bi ijọba ko ṣe ni in lọkan lati pese aabo fun wọn, bẹẹ lo pọn dandan ki wọn pese aabo to yẹ funra wọn.

Leave a Reply