Wọn ti mu Emir, ọmọ ẹgbẹ okunkun to n jale l’Ọbada-Oko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Fatai Ibrahim lorukọ ẹ, ṣugbọn Emir lawọn eeyan to n da laamu l’Ọbada-Oko, nipinlẹ Ogun, mọ ọn si. Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ẹ bayii, nitori wọn ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni, bẹẹ lo n jale, to tun lọwọ si wahala END SARS lọdun to kọja.

Lori eyi ti wọn fi mu un lọjọ kẹwaa, oṣu keji yii, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye pe Emir da Tijani Sọdiq lọna, lọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun 2021, lopopona Ararọmi, l’Ọbada-Oko.

O ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira (120,000) lo gba lọwọ Tijani pẹlu nnkan ija, to tun ṣe e leṣe, bẹẹ lo gba irẹsi apo meji tiyẹn n gbe lọ lọwọ ẹ.

Ọjọ karun-un lẹyin iṣẹlẹ naa ni Tijani kofiri Emir l’Obada, lo ba sare lọọ sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa, bi wọn ṣe wa Emir ri niyẹn, ti wọn mu un ṣinkun.

Awọn ọlọpaa sọ pe iwadii fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni, wọn ni oun lo ko awọn janduku lẹyin lasiko End SARS, ti wọn lọọ ba teṣan ọlọpaa Ọbada-Oko jẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Bẹẹ ni wọn lo ti jẹwọ pe oun mọ nipa awọn idaluru oriṣiiriṣii to n ti ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun waye l’Ọbada.

Ni bayii, wọn ti taari afurasi naa lọ sẹka itọpinpin to lọọrin, nibẹ ni yoo gba dele-ẹjọ.

Leave a Reply