Ọga agba Poli Ado-Ekiti pariwo: Irọ ni wọn n pa, emi o ṣe owo ileewe baṣubaṣu o

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Wahala nla lo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde to kọja, nileewe poli ijọba apapọ, iyẹn Federal Polytechnic, Ado-Ekiti, pẹlu bi awọn olukọ kan labẹ ẹgbẹ Academic Staff Union of Polytechnics (ASUP) , ṣe ti geeti pa, ti wọn ko jẹ ki idanwo to yẹ ko bẹrẹ lọjọ naa waye.

Ẹsun ti olori ASUP, Ọmọwe Ọlabisi Ọlasẹinde, fi kan ọga-agba ileewe naa, Ọmọwe Hephzibah Ọladebẹyẹ, ni pe ko sanwo fawọn olukọ to n kọ awọn akẹkọọ irọlẹ (Part-time), bẹẹ lo ti fi biliọnu kan naira to yẹ ko fi sanwo gbogbo oṣiṣẹ ṣòwò igbalode Bitcoin.

Eyi lo da rogbodiyan silẹ nileewe naa nitori ṣe lawọn olukọ ọhun fẹsun oriṣiiriṣii mi-in to jẹ mọ eto inawo ninu ọgba naa kan an, arọwa si pọ ki wọn too pada ṣi geeti ileewe naa.

Nigba to n fesi si awọn ẹsun wọnyi, Ọladebẹyẹ ṣalaye pe owo awọn to n kọ ẹkọ irọlẹ nikan nileewe ọhun n san, ki i ṣe owo gbogbo olukọ, nitori iṣẹ ijọba apapọ ni, ọda owo lo si da ifasẹyin diẹ silẹ. O ni awọn eeyan naa kan deede da wahala ọhun silẹ ni lai tẹle ofin ẹgbẹ wọn, eyi si ta ko ofin iṣẹ ijọba gan-an.

Ọga-agba naa ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, ni wọn deede ṣepade pajawiri kan, ọjọ naa lo si kangun si ọjọ ti wọn fẹẹ bẹrẹ idanwo nitori ọjọ Ẹti ni, ọjọ Aje to tẹle e lo si yẹ ki idanwo bẹrẹ. O ni ilu Abuja loun wa nigba tiṣẹlẹ naa waye, eyi to jẹ koun paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo owo to ba wa nilẹ jọ, ki wọn si sanwo naa.

 

O ni, ‘‘Kia ni mo ni ki wọn sanwo fawọn olukọ yii, bẹẹ ni mo ni ki wọn ma san tawa igbimọ alaṣẹ nitori tiwa naa wa nibẹ. Laarin ọjọ Satide si Sannde ni eyi waye, ṣugbọn ṣe la tun ṣakiyesi pe awọn aṣiṣe kan wa. Iyalẹnu lo jẹ pe pẹlu eyi, wọn tun pada ṣe nnkan ti wọn ṣe lọjọ Aje.

‘‘Awọn owo ta a n ri labẹle la fi n ṣe ọpọ nnkan ta a n ṣe, bẹẹ la tun fi n san iru owo ti wọn n ja fun yii. Ibi ti wọn ti ri biliọnu kan ti mo gbe sori Bitcoin ko ye mi rara nitori ko si iru owo bẹẹ nileewe yii, mi o si mọ nnkan to n jẹ Bitcoin.

‘‘Gbogbo wahala ti wọn da silẹ yẹn ko tiẹ ba ofin mu, bẹẹ lo ni ijiya ninu. O yẹ ki wọn tiẹ kọkọ fun wa ni ọjọ mọkanlelogun, ọjọ mẹrinla ati ọjọ meje gẹgẹ bii ofin to de ASUP funra ẹ, ṣugbọn wọn ko ṣe iyẹn. Titipa si ofin gbaa lọrọ to wa nilẹ yii.’’

ALAROYE gbọ pe awọn alaṣẹ ileewe naa pada fun awọn olukọ ọhun niwee sọ-tẹnu-ẹ lori ẹsun pe wọn ko jẹ ki idanwo waye, ati nitori pe wọn tapa si ofin.

Ṣugbọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ-jade ileewe naa da si ọrọ ọhun pẹlu ẹbẹ pe ki igun mejeeji fọwọ sowọ pọ ki orukọ ileewe naa ma baa bajẹ lawujọ.

Alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Abiọdun Oyedokin, sọ pe awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ati ibanilorukọjẹ gbọdọ dopin fun anfaani orukọ rere ti Poli Ado-Ekiti ni ati fun awọn akẹkọọ to yẹ ko ṣedanwo ki wọn le maa lọ sile.

Oyedokun fọwọ sọya pe ọga-agba ileewe naa ti ṣe awọn nnkan ribiribi lori igbaye-gbadun awọn olukọ lori ọrọ igbega, ẹyawo ati ajẹmọnu. O ni Ọladebẹyẹ ko le kowo jẹ, iru awọn ẹsun ti wọn fi n kan an yii yoo kan ba orukọ ileewe naa jẹ lawujọ ni.

Leave a Reply