Kootu Majisireeti agba to wa n’Iyaganku, n’Ibadan, ti paṣẹ pe kawọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta ti wọn lọọ mu Wakili Iskilu, ogboloogboo Fulani to n daamu Ibarapa, maa lọ sọgba ẹwọn Abolongo, n’Ibadan, nitori wọn lufin igbimọpọ, ipaniyan ati mi mọ-ọn-mọ dana sunle onile.
Ọjọruu ọsẹ yii ti i ṣe Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹta ni Adajọ Agba Ọlaide Hamzat, paṣẹ pe ki Awodele Adedigba;ẹni ọdun marundinlaaadọta,(45),Dauda Kazeem; ẹni ọdun mejidinlogoji (38) ati Hassan Ramọn; ẹni ọdun mẹtalelọgbọn(33) ti wọn lọọ mu Wakili nile rẹ lọjọ keje oṣu yii, maa lọ si ẹwọn Abolongo na titi digba ti igbẹjọ mi-in yoo waye lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹrin ọdun 2021.
Adajọ Hamzat ko gba ipẹ awọn OPC mẹta yii, o ni ko lẹsẹ nilẹ. Ohun ti ẹni to n rojọ tako awọn olujẹjọ, Inspẹkitọ Ọpẹyẹmi Ọlagunju, sọ lori ẹjọ naa ni pe awọn olujẹjọ mẹta yii, ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ keje, oṣu kẹta ọdun 2021, ṣeku pa obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan ni Abule Kajọla, l’Ayẹtẹ, Ibarapa nipinlẹ Ọyọ, iyẹn nigba ti wọn gbimọ pọ wọ ile Wakili. Koda, o ni wọn tun dana sun ile baba naa, ile ọhun si to miliọnu marun-un naira.
Ẹsun tawọn OPC yii n jẹjọ ẹ, lodi si abala ikẹrinlelọọọdunrun(316), ọọdunrunlemẹrinlelogun(324) ati irinwo le mẹrinlelogoji (443)ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọyọ ti wọn ṣe lọdun 2000, o si ni ijiya ninu gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi.
Ẹ oo ranti pe ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni ikọ OPC, igun Iba Gani Adams, lọọ mu Wakili, ti wọn ni ko jẹ kawọn ara Ayẹtẹ lọ soko wọn mọ. Ṣugbọn mimu ti wọn mu un naa di wahala, nitori awọn ọlọpaa lodi si i, wọn ni baba naa ko gbadun, o ṣeṣẹ lọọ gba itọju de lorilẹ-ede Olominira Benin ni, ko si ti i fara balẹ silẹ rẹ tawọn OPC fi kọlu u, ti wọn pa obinrin kan, ti wọn tun dana sun ile Wakili.
Awọn OPC naa fesi lasiko naa, wọn lawọn ko paayan nile Wakili, wọn ni awọn ọmọ ogun ọkunrin naa lo kọkọ yinbọn mọ awọn. Ati pe ẹni to ku ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ohun ti awọn ba lọ s’Ayẹtẹ, wọn ni Wakilu to sọ ara ẹ dọba mọ wọn lọwọ lawọn wa lọ.