Nibi ti mo ba a de yii, nnkan to maa ṣe ilu lanfaani ni mo maa ṣe, nitori ọpọ nnkan ni mo ri ti ẹyin ko ri

Mi o lẹru kankan lọfiisi, ibi ti mo ba ti gbọ pe wọn ti yọ mi nipo gomina naa ni ma a gba pada sile -Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde ti sọ pe ẹru ko ba oun rara lati fi ipo ọla ti oun wa yii silẹ, ojoojumọ loun n huwa bii ẹni ti ko ni i di ọjọ keji lọfiisi.

Nibi ipade ti awọn asaaju Yoruba ṣe lori eto aabo ni gbọngan Mapo, n’Ibadan, lo ti sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

O ni nibi ti ọrọ eto aabo de duro yii, ijọba oun ti ṣetan lati da ikọ eleto aabo mi-in silẹ. O ni aladaani ni ikọ eleto aabo yii yoo jẹ, o ni ọna ti wọn yóò máa gbà gba awọn eeyan sibẹ yoo yatọ si ti Amọtẹkun patapata.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ” Ti wọn ba yọ mi nipo gomina, ibi ti iroyin yẹn ba ti ba mi naa ni ma a rọra gba pada sile jẹẹjẹ. Ko si ohun to tun le ba mi lẹru nipa ipo mọ nitori ẹẹmẹta ni mo ti dupo ti mo si fidi-rẹmi. Mo dupo lọdun 2007, mo fidi rẹmi; mo du u lọdun 2015, mo tun fidi rẹmi, ko too di pe mo wọle lọdun 2019. Ki lẹ waa lero pe o tun le maa ba mi lẹru. Mi o ni baba isale oṣelu yatọ si Ọlọrun funra rẹ to gbe mi depo.

‘‘Nibi ti mo ba a de yii, aimọye nnkan lemi ti ri ti ẹyin o le ri. Ṣugbọn nnkan to maa ṣe ilu lanfaani ni mo maa ṣe.

“Ọrọ idibo 2023 kọ lo wa nilẹ yii. Bawo la ṣe fẹẹ ṣe e ti ohun to tọ si kaluku ṣe maa kan an ni Naijiria lo yẹ ka mojuto. Ẹ jẹ ka fọgbọn ṣe nnkan to wa nilẹ yii nitori ti a ko ba lo ọgbọn, ki Ọlọrun ma jẹ ka kabaamọ.

Bi mo ṣe duro yii, ti wọn ba sọ pe mi o se gomina mọ, ibi ti mo wa naa ni ma a gba dele, nitori mi o ni dukia kankan lọfiisi, bi mo ṣe n lọ ti mo n bọ ni mo n gbe baagi mi lọ si ọfiisi.’’

Makinde sọ pe ijoba oun yoo da ikọ eleto aabo mi-in sile yatọ si Amọtẹkun lati le mu ki eto aabo dara si i.

Ninu agbekalẹ eto aabo ipinlẹ Ọyọ, a ti ri i pe a nilo eyi ti ko ni i lọwọ awọn ọmọ eeyan to laamilaaka ni ipinle yii ninu (state actor) nitori nigba ta a da Amọtẹkun silẹ, awọn eeyan n pariwo pe ẹgbẹ kan la gba ju, ẹgbẹ eyi lo po ju nibẹ. Iyẹn aa jẹ pe awọn ni wọn maa jọwọ ara wọn lati ṣe e. Ijọba nikan o le da a ṣe.

Makinde ni gbogbo ohun to ba yẹ ki oun ṣe gẹgẹ bii gomina, gẹgẹ bii Ṣeyi Makinde, ati gegẹ bii ọmọ Yorùbá loun maa ṣe.

Lara awọn to kopa nibi apero ọhun ni aṣoju Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ati aṣoju Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi. Diẹ lara awọn to tun kopa nibẹ ni: Ọba Ọlanrewaju Ajayi ti i ṣe ọba ilu Igbomina Ekiti, nipinlẹ Kwara; Ọgbẹni Tunji Alapinni, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba ọlọpaa lorileede yii; Ọjọgbọn Sọji Adejumọ, ẹni to ti figba kan jẹ alaga igbimọ to n ṣakoso eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ; Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbu-ibọn; Sheik Abdul Raheem Aduranigba ti i ṣe imaamu awọn Yoruba n’Ilọrin atawọn mi-in bẹẹ, titi dori Oloye Alao Adedayọ ti i ṣe oludari agba iweeroyin ALAROYE .

 

 

Leave a Reply