Maaluu mọkanlelaaadọta ku lojiji l’Akungba Akoko, n lolowo wọn ba bu sigbe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayeefi lo si n jẹ fawọn eeyan ilu Akungba Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, lori ohun ṣe iku pa awọn maaluu bii mọkanlelaaadọta nile olowo wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye lagbegbe ileewe girama A. U. D, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa.

Akọroyin wa fidi rẹ mulẹ lati ẹnu araalu kan ta a forukọ bo lasiiri pe igbe nla tawọn eeyan agbegbe naa gbọ ti ọkunrin to ni awọn maaluu ọhun, Ibrahim Saliu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Baba Saliu, n ke ni wọn fi rọ giiri lọ sile rẹ lati mọ ohun to n pa a nigbe.

O ni iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan lati ba oku awọn maaluu Fulani ọhun nilẹ rẹrẹẹrẹ ninu ọgba ile rẹ.

O ni ọrọ iku awọn maaluu naa ti da jinnijinni nla bo gbogbo awọn araalu Akungba, nitori ibẹru pe o ṣee ṣe kawọn Fulani fẹẹ waa gbẹsan ohun to sẹlẹ naa lara wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alalẹ tilu Akungba, Ọba Sunday Ajimọ, ni ilu ti n gbe igbesẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iku to pa awọn maaluu ọhun lojiji.

Ọba Ajimọ ni oun ti kilọ fun ọkunrin to ni maaluu ọhun lati ma ṣe gbiyanju ati ta a fun ẹnikẹni nitori ilera awọn araalu.

O ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o n ta ẹran eyikeyii ninu awọn maaluu ọhun fawọn eeyan ko ni i sai foju wina ofin.

 

 

Leave a Reply