Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, ti ṣalaye idi to ṣe ko ẹgbaagbeje ọlọpaa lọ si gbọngan Mapo, nibi ti ọkẹ aimọye awọn ọmọ Yoruba pe jọ si lati sọrọ lori ominira ilẹ Yoruba.
Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja lawọn ẹgbẹ ajijagbara Yoruba loriṣiiriṣii pe jọ si gbọngan Mapo, nIbadan, lati ṣe iwọde kaakiri igboro ilu naa, lati jẹ ki gbogbo aye mọ ibi ti nnkan de duro lori ominira ilẹ Yoruba ti wọn n ja fun, ṣugbọn to jẹ pe nnkan bii aadọta (50) ọlọpaa lo ti gbakoso gbọngan Mapo ti wọn ti fẹẹ pade ṣaaju iwọde naa mọ wọn lọwọ, bo tilẹ jẹ pe wọn pada ṣeto ọhun lai si wahala.
Nigba to n sọrọ nibi apejọ naa, akọwe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Baṣọrun Kunle Adeṣọkan sọ pe “a ti bẹrẹ igbesẹ lati gba ominira ilẹ Oodua, ko si ohun tabi ẹnikẹni to le da wa duro lori ẹ.
“Gbogbo awọn oloṣelu to n ta ko idasilẹ orileede Olominira Oodua nitori ipo oṣelu ọdun 2023 ti wọn n wa n tan ara wọn jẹ ni nitori eto idibo kankan ko wulẹ ni i waye ni Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba.
A ko tori oloṣelu kankan wa nibi. Nnkan ta a wa sibi fun ni Ominira orileede Oodua, nitori Naijiria ti su wa pẹlu bo ṣe jẹ pe inu iṣẹ atoṣi ni eto iṣejọba Naijiria ko wa si, nibi ti awọn akẹkọọ-gboye ti n gun ọkada nitori ti ko si iṣẹ nita.”
Nigba to ba ALAROYE sọrọ nipa eto naa, CP Onadeko, ẹni to sọrọ nipasẹ DSP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, sọ pe bo tilẹ jẹ awọn to ṣe iwọde naa ko fi igbesẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti ki wọn too gun le e, sibẹ kiko ti oun ko awọn ọlọpaa lọ sibẹ ki i ṣe nitori ki wọn ma baa ri iwọde naa ṣe.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ọlọpaa ko di iwọde yẹn lọwọ rara. Iṣẹ ọlọpaa ni lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu. Gẹgẹ bii iriri wa lẹnu lọọlọọ yii, ọpọ iwọde to ba ti ko eeyan rẹpẹtẹ sinu lawọn tọọgi maa n ja gba mọ wọn lọwọ, ti wọn yoo si ba erongba rere awọn oluwọde jẹ pẹlu iwa idaluru eyi to le la ofo ẹmi ati dukia lọ.
“Labẹ ofin Naijiria, ẹtọ araalu ni lati ṣewọde alaafia tabi lati beere fun ẹtọ wọn, ṣugbọn nitori awọn iriri ta a ti ni nipa bi awọn ọmọ ita ṣe maa n lo anfaani iwọde lati da omi alaafia ilu ru, lawọn ọlọpaa ṣe lọ si Mapo lati dara pọ mọ awọn to fẹẹ ṣewọde naa, ki awọn tọọgi ma baa gbakoso kinni yẹn mọ wọn lọwọ.”
Lati ipinlẹ gbogbo nilẹ Yoruba lawọn to kopa nibi eto naa ti wa, titi dori awọn ẹya Itsẹkiri, atawọn ara ipinlẹ Edo, Delta ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn eeyan pataki to kopa nibi eto ọhun ni gbajugbaja obinrin oṣere tiata Yoruba nni, Oloye Anikẹ Bọla Obot, Ọmọwe Kunle Amzat ati bẹẹ bẹẹ lọ.