Faith Adebọla, Eko
Gbajugbaja alawada to wa lahaamọ ọlọpaa fẹsun fifipa ba ọmọde ṣeṣekuṣe nni, Ọgbẹni Ọlanrewaju James, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ti binu kọ ounjẹ silẹ lahaamọ ọlọpaa ti wọn fi i si ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, bẹẹ ọkunrin naa ki i ṣe Musulumi, ko si gbaawẹ to n lọ lọwọ yii.
Gbara ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ, tawọn agbofinro ti lọọ fi pampẹ ọba mu Baba Ijẹṣa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ ki wọn taari ẹ si ẹka to n gbọ ẹsun to jẹ mọ iwa ọdaran abẹle, lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ibẹ ni wọn ti n ṣiṣẹ iwadii lori ẹsun ọhun.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa ti kọ ounjẹ silẹ, wọn ni ko jẹ ounjẹ tawọn mọlẹbi rẹ n gbe wa, ko so gba ounjẹ tawọn agbofinro n gbe fun un.
Bakan naa ni wọn lo ti jẹwọ fawọn agbofinro to n ṣewadii lori ọrọ ọhun, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe afurasi ọdaran naa fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn to n ṣewadii ọrọ naa, wọn lo ti ṣalaye bi iṣu ṣe ku ti ọbẹ si bẹẹ fun wọn, ati pe wọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ.
Ṣaaju ni ọpọ awọn ololufẹ Baba Ijẹṣa ti kọyin si i lori ẹsun ifipa bọmọde lo pọ ti wọn fi kan an,