Stephen Ajagbe, Ilorin
Igbakeji abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Kwara, Ọnarebu Adetiba-Ọlanrewaju Raphael, ti ba gbogbo ẹbi ati araalu Isapa, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, kẹdun iku Onisapa tilu Isapa, Ọba Raphael Oguntọla Alayande, Ilufẹmiloye Kin-in-ni, ẹni to waja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Adetiba ni o jẹ ohun ibanujẹ nla bi ilu ṣe padanu kabiyesi naa, nitori pe lasiko to wa laye, ọrọ awọn ọdọ jẹ ẹ logun gidi, o si maa n gbaruku ti awọn to ba nifẹẹ si eto idagbasoke ilu.
Ọnarebu Adetiba ni; “Ọkan lara awọn ọba ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ni Ọba Raphael, oun lo fi oye Aarẹ Tayeṣe tilu Isapa da mi lọla. A maa ṣedaro ẹni nla to lọ naa. Idagbasoke ilu jẹ ẹ logun gidi, o si nigbagbọ ninu ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba fun igbaye-gbadun araalu.”
O loun ba Ọnarebu Ganiyu Abọlarin kẹdun, o si gbadura ki Ọlọrun tu awọn ti ọba naa fi silẹ saye lọ ninu.