Faith Adebọla
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ ta a wa yii, nijọba ipinlẹ Eko kede pe kawọn akẹkọọ ọlọdun mẹta akọkọ nileewe girama, (JSS3) pada sileewe ni igbaradi fun idanwo wọn.
Atẹjade kan lati ọfiisi Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, lo sọ eyi di mimọ. O ni ijọba paṣẹ iwọle naa ko baa le ṣee ṣe fawọn akẹkọọ ti wọn ti forukọ silẹ fun idanwo aṣekagba Basic Education Certificate Examination (BECE) eyi ti ajọ National Examination Council (NECO) yoo ṣe fun wọn, le mura silẹ de idanwo ọhun ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii kan naa.
Ninu atẹjade ọhun, kọmiṣanna naa ṣalaye pe kiki awọn to ti forukọ silẹ lati ṣedanwo NECO-BECE yii ni yoo wọle lọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ yii, ki awọn to jẹ idanwo ti Lagos State Education Board (LSEB-BECE) ni wọn forukọ silẹ fun ma ti i wọle. Wọn ni ijọba yoo maa kede asiko ti idanwo tiwọn yoo waye lọjọ iwaju.
O fi kun un pe awọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa lọ lati ileewe kan si omi-in, titi kan tawọn aladaani, lati wo bi wọn ṣe pa aṣe ati alakalẹ Korona mọ si. Komiṣanna ni loju ẹsẹ lawọn yoo maa fiya jẹ ileewe to ba kuna lati tẹle awọn alakalẹ ati ofin tijọba ṣe fun idaabo awọn akẹkọọ lasiko Korona yii.
Lara awọn alakalẹ to lo pọn dandan ni pe ki akẹkọọ ati olukọ lo ibomu nigba gbogbo, ki wọn fi ẹrọ ṣayẹwọ igbona fẹnikẹni to ba fẹẹ wọnu ọgba ile-ẹkọ, ki awọn akẹkọọ ma ṣe ju ogun lọ ninu kilaasi kan, ko si tito sori ila laaarọ, bẹẹ ni wọn gbọdọ pese ifọwọ apakokoro, ọṣẹ ati omi ni gbogbo ayika ileewe.