Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ninu akitiyan wọn lati lọwọ si alaafia araalu, ki wọn si ran ijọba lọwọ, ijọ Onirapada ti wọn n pe ni Ridiimu, ti pese aaye itọju aisan kindinrin si ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, bẹẹ ni wọn si ra irinṣẹ ti wọn yoo maa lo nibẹ si i.
Ọjọbọ, ọjọ karun-un oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni Gomina Dapọ Abiọdun, ṣi ileetọju naa ti wọn pe orukọ ẹ ni ‘Enoch and Folu Adeboye Dialisis Centre’, pẹlu ọrọ iwuri to ti ẹnu Igbakeji ẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, to ṣoju rẹ wa.
Gomina Abiọdun sọ pe agbekalẹ bii eyi yoo ran ijọba lọwọ lati wa alaafia faraalu si i. O ni nigba ti awọn ileejọsin atawọn olufẹ idagbasoke mi-in ba n kun ijọba lọwọ bii eyi lati pese itọju, ko si bi ẹka ilera ko ṣe ni i gbera sọ. O dupẹ lọwọ ijọ Onirapada fun ohun ti wọn ṣe yii, bẹẹ lo ni ijọba oun ko ni i da iṣẹ naa da awọn oluranlọwọ bii eyi, awọn yoo maa ṣe aṣekun mọ eyi tawọn n ṣe lọ ni.
Irinṣẹ itọju aisan kindinrin ti wọn ko saaye naa ni ẹrọ kan to n tọju omi ti wọn yoo lo fun alaisan, eyi to n fọ omi naa mọ gaara ati ẹrọ amunawa jẹnẹretọ ti wọn yoo maa fi lo o bi ina ọba ba lọ.(30kva generator)
Lara awọn to tun wa nibẹ lọjọ naa ti wọn fi idunnu wọn han si eto yii ni Dokita Tomi Coker, iyẹn kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Ogun, pẹlu Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi.
Gbogbo wọn ni wọn fi atilẹyin wọn han si igbesẹ yii, ti wọn dupẹ lọwọ ijọ Ridiimu fun iranlọwọ naa, pẹlu ileri pe ijọba yoo maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹka aladaani to ba fẹẹ ṣe iru eyi, wọn si gba a laduura pe oke ti ọwọ afunni n gbe lọwọ wọn yoo maa lọ.
Akarigbo rọ awọn oninu-dundu ọlọrẹ lati dide, ati awọn ẹka aladaani naa, ki wọn ran ijọba Gomina Dapọ Abiọdun lọwọ lati pese ọjọ iwaju rere to pilẹ rẹ lati mu wa fun ipinlẹ Ogun.
Adele ọga pata ni OOUTH, Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe, sọ ninu ọrọ tiẹ pe ile itọju aisan kindinrin yii yoo jẹ ibi iranlọwọ fawọn araalu ti aisan naa ba n da laamu, ti wọn ko si lowo gidi ti wọn yoo fi tọju ara wọn lawọn ọsibitu olowo gegere.