Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ kan to n fapa janu ninu ẹgbẹ oṣelu Onitẹsiwaju, APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ya lọ sinu ẹgbẹ oṣelu miiran, iyẹn YPP, nipinlẹ ọhun, lẹyin ti wọn kọkọ lọ si ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn n pe ni (Third Force).
Nigba ti alakooso ẹgbẹ oṣelu (Third Force), to tun jẹ adari ẹgbẹ oṣelu APC ni Aarin Gbungbun ipinlẹ Kwara, tẹlẹ, Abdulfatah Abdulrahman, n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin, o ni oun rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa ju lọ awọn ọdọ, lati waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu tuntun yii, ki wọn gbe e larugẹ, ki wọn si dan an wo lasiko yii, ki igba ọtun le wọle de ni ipinlẹ Kwara.
O tẹsiwaju pe ohun to mu ki awọn ya kuro ninu ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ nni APC, ni gbọn-mi- si i, omi-o-to-o, to n ba ẹgbẹ ọhun fínra ati bi wọn ṣe yan awọn oloye ẹgbẹ kaakiri wọọdu ni Kwara lọna aitọ, to si han pe ẹgbẹ ọhun ti wo patapata ni ipinlẹ Kwara, bayii.
Alaga ẹgbẹ oṣelu YPP, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Charles Folayan, ki wọn kaabọ, o si gba wọn tọwọ tẹsẹ sinu ẹgbẹ, o waa juwe idarapọ mọ ẹgbẹ ọhun bii ẹri to daju pe wọn ti ri imọlẹ, ti ẹgbẹ yii si ti setan lati tun orile-ede Naijiria ati ipinlẹ Kwara ṣe, ti gbogbo wara ati oyin to ti lọ yoo si pada wa, ti yoo si fi opin si awọn ti ko kunju oṣunwọn ti wọn n sejọba lorile-ede yii.