Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ariyanjiyan rẹpẹtẹ lo waye lẹyin iku Imaamu agbegbe Atiba, n’Ijẹbu-Ode, iyẹn Sheikh Muṣafau Bakare. Ẹni ti wọn lo jade nile rẹ l’Ọjọruu, ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ti ko si wọle mọ, to jẹ oku ẹ ni wọn ri lọjọ keji ti i ṣe Ọjọbọ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe awọn ajinigbe agbebọn kan gbe e lọ ni lawọn mi-in n sọ pe ko ri bẹẹ. Wọn ni baba naa jade funra rẹ ni, iku ka a mọ oju ọna, ko si le wale mọ, ko too di pe wọn waa ri oku rẹ lọjọ keji, nibi kan ti wọn n pe ni Ikangba, nijọba ibilẹ Odogbolu.
Iroyin to kọkọ gbode ni pe awọn ajinigbe agbebọn lo waa gbe Imaamu agba Atiba lọ, ti wọn pa a tan, ti wọn si gbe oku ẹ sinu mọto ayọkẹlẹ Toyota Highlander jiipu to sẹṣẹ ra.
Ṣugbọn Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe ko ri bẹẹ rara. Ọlọpaa yii sọ pe ọrọ ajinigbe ko tiẹ ṣẹlẹ ninu iku baba yii.
Oyeyẹmi sọ pe ode ni Imaamu lọ, nigba to yẹ ko ti pada de ti ko wale lawọn ẹbi rẹ lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa.
O ni awọn ẹbi ti pe nọmba baba naa titi, niṣe lo wulẹ n dun lasan ti ko gbe e, iyẹn ni wọn ṣe lọọ fejọ sun ni teṣan ọlọpaa.
O tẹsiwaju pe ikọ ọlọpaa kan to n wọde lọ lo ri mọto jiipu kan ti wọn paaki sẹgbẹẹ ọna nigba ti wọn n lọ, bakan naa lọkọ ọhun tun ṣe wa nibẹ nigba ti wọn n bọ, ni wọn ba fi duro, wọn ṣilẹkun ọkọ ọhun wo, wọn si ba oku agbalagba kan nibẹ, aṣe ti Imaamu Muṣafau ti wọn ti n wa ni.
Ko si apa kankan lara oku naa bi Oyeyẹmi ṣe wi, eyi to fi han pe ko sẹni to fọwọ kan an tabi ṣe e ni ṣuta to fi ku.
O ni ohun tawọn gbọ ni pe baba to le lọgọta ọdun yii ni aisan ẹjẹ riru, o ṣee ṣe ko jẹ wahala ẹjẹ riru naa lo ṣẹlẹ si i lojiji, to si gba ẹmi ẹ sibẹ, ṣugbọn ki i ṣe pe wọn ji i gbe, bẹẹ ni ẹnikẹni ko yin in nibọn.
Ṣa, wọn ti sinku baba naa l’Ọjọbọ, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.