Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iya to bi ọdọmọkunrin onifuji nni, Rasheed Atanda tawọn eeyan mọ si Shanko Raṣidi, ti ku o.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii, ni iya to n jẹ Tayelolu, naa dagbere faye.
Ṣanko Raṣidi funra ẹ lo kede iku iya re lawọn oju opo ayelujara rẹ, ohun to kọ sibẹ ni pe ọdọ Ọlọrun la ti wa, ọdọ rẹ naa la oo si pada si.
“Ọpẹ ni fun Ọlọrun, a o ni agbara kankan ta a le fi da yin duro saye lọdọ wa titi aye, Maami oninuure, oniwa ire, ejirẹ mi, Tayelolu Oyila. Winni winni loju orogun, ẹjiwọrọ loju iya ẹ. Ọmọ Ijẹṣa ẹlẹni atẹẹka, ọmọ ẹlẹni ẹwẹlẹ.
Ọmọ ẹru ọwa, ọmọ Obokun. Sun un ree, Iya Atanda Ṣanko Raṣidi. Inu ibanujẹ nla ni mo wa bayii, ṣugbọn mo ṣi gbọdọ dupẹ f’Ọlọrun naa ni.”
Latigba to ti kede iku iya naa lawọn eeyan ti n ba oṣere to n kọ Fuji ati orin sufee-taka naa kẹdun, ti wọn n sọ pe Ọlọrun yoo tẹ iya rẹ safe rere.