Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ṣe ni iku arabinrin ọlọmọ mẹfa kan, Jimoh Fatimoh, n ṣe awọn mọlẹbi rẹ ni kayeefi, tori pe obinrin naa ṣẹṣẹ gba idọti tan ni, to si lọọ da a nu si aakitan, ṣugbọn ṣe ni obinrin ọhun gbe igba idọti kalẹ si ẹgbẹ kan, oku ẹ ni wọn gbe jade ninu odo kan to ko si ni agbegbe Ajibẹsin Ogidi, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe Agboole Okoh, ni Abata Asunkẹrẹ, nile ọkọ arabinrin ọhun, ṣugbọn ti wọn n gbe ni agbegbe Ajibẹsin, nibi ti ọkọ rẹ kọle si. Ọmọ mẹfa ni obinrin naa bi, kọda, lọjọ to ko sodo yii gan-an ni ọkọ afẹsọna akọbi rẹ fẹẹ waa yọju si wọn. Ileekewu aafaa kan ti wọn n pe ni Alufaa Ọlọwọ, ni wọn ni obinrin yii ti n ṣiṣẹ, o maa n ba wọn gba ilẹ ileekewu ọhun ni, ibẹ naa lo ti lọọ ṣiṣẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, to fi lọọ bẹ sodo.
Titi di igba ta a n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to mọ idi ti obinrin naa fi bẹ sodo, wọn si ti sinku rẹ nilana ẹṣin Musulumi.