Arẹgbẹsọla rọ awọn ẹlẹwọn to sa lọ ni Kogi lati pada sọgba ẹwọn kiakia

Faith Adebọla, Eko

Minisita fun ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Aregbẹṣọla, ti ṣekilọ fawọn ẹlẹwọn ti wọn jakun nipinlẹ Kogi lọjọ Aiku, Sannde yii, pe ki wọn finu findọ lọọ fara han ni agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn tabi ki wọn pada sọgba ẹwọn naa jẹẹjẹ, ti wọn ba fẹran ara wọn.

Arẹgbẹsọla ni gbogbo igbesẹ to pọn dandan nijọba ti bẹrẹ si i gbe lori awọn awọn ẹlẹwọn atawọn afurasi ọdaran ti wọn sa lọ ọhun, titi kan lilo awọn ọlọpaa agbaye ti wọn n pe ni INERPOL, lati fi pampẹ ofin mu eyikeyii ti wọn ba ri ninu wọn, ibaa jẹ lẹyin odi ilẹ wa paapaa.

Ọjọ Aje, Mọnde yii, ni minisita to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ sọrọ ikilọ ọhun latẹnu Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Ṣọla Fasure, latari iṣẹlẹ fifọ ọgba ẹwọn MSCC (Medium Security Custodial Centre) to wa niluu Kabba, nipinlẹ Kogi, wọn lawọn agbebọn kan ni wọn ṣiṣe buruku naa.

Minisita naa fidi ẹ mulẹ pe ẹlẹwọn ọọdunrun o din mẹrin (294) lo wa lahaamọ lasiko akọlu ọhun, ṣugbọn mejidinlọgbọn pere lo ṣẹku nigba ti rukerudo naa yoo fi rọlẹ, o lawọn tun padanu ṣọja kan ati ọlọpaa kan tawọn janduku naa mu balẹ, awọn ṣi n wa awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ọhun meji, boya wọn ti ku tabi wọn ṣi wa laaye, awọn o ti i le sọ.

“A fẹ kẹyin araalu lọọ fọkan balẹ lori iṣẹlẹ yii, gbogbo igbesẹ to tọ la ti n gbe lati ri i pe awọn ẹlẹwọn to sa lọ naa ko ni i di wahala saarin ilu, igbimọ amuṣẹya kan (CRC) ti bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ lori wọn.

Gbogbo ohun to ba gba la maa fun un, gbogbo ọna la maa ṣan lati ri i pe a wa awọn to sa lọ yii ri mu pada, koda a ti fi to awọn ọlọpaa agbaye (INTERPOL) leti pẹlu, boya a le ri lara wọn to fẹẹ gbọna ẹyin odi sa lọ. A fẹ kẹyin araalu tete ta awọn agbofinro leti tẹ ẹ ba ti ri ẹnikẹni ti irisi ati irinsẹ rẹ mu ifura dani laduugbo yin.

Ni ti ẹyin ẹlẹwọn yii, mọ rọ yin pe tẹ ẹ ba fẹran ara yin, ẹ pada sọgba ẹwọn jẹẹjẹ, a maa fọwọ jẹlẹnkẹ mu ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ, tabi kẹ ẹ lọọ fi ara yin han ni teṣan ọlọpaa to sun mọ ibikibi tẹẹ wa, aijẹ bẹẹ, ori ọka lẹ fi n họ’mu ni gidi.”

Minisita naa lo ṣekilọ bẹẹ.

Leave a Reply