ỌMỌỌDỌAGBA
Nibikibi ti ẹmi ọkunrin oyinbo ti wọn n pe ni Lord Lugard ba wa, Ọlọrun ko ni i fi ẹmi ẹ lọkan balẹ, arinkiri ni yoo maa ba a, bo ti n wọ inu ẹranko ni yoo maa wọnu ina, réderède bẹẹ, pẹlu iya nla, ni yoo jẹ ẹmi ọkunrin naa titi ti ọjọ idajọ Ọlọrun yoo fi de, yoo si jẹ ọkan ninu awọn ti ko ni i ba oju rere Ọlọrun pade! Yato si bẹẹ, awọn arọmọdomọ rẹ ko ni i nisinmi, nibi yoowu ki wọn gba, ọna yoowu ki wọn tọ, iya aburu ti baba nla wọn ṣe yii yoo maa jẹ wọn kaakiri. Bo si pẹ bo ya ni o, orilẹ-ede Britain naa yoo pada jiya ohun ti wọn ṣe fun Naijiria, ọjọ n bọ ti wọn yoo jiya ẹs wọn. Ọjọ n bọ ti ipo agbara maa bọ kuro lọwọ wọn, ti wọn aa kuro ni ipo aṣaaju aye, ti wọn aa d’ero ẹyin, won ko si ni i bọ ninu ipo ẹru yii fun ọdun pupọ, nitori hilahilo aa ba wọn nitori aburu wọn. Ọrọ mi yii le da bii àsé lasan, tabi ko da bii ikanra tabi ibinu odi, ṣugbọn bo ti maa ri niyi pẹlu agbara Ọlọrun.
Naijiria ko ni isinmi. Awa eeyan ibẹ ko ni isinmi. Naijiria ko gbadun. Awa eeyan ibẹ ko gbadun. Ojumọ kan, wahala kan ni. Ija buruku mi-in ti tun bẹrẹ bayii laarin awọn gomina ati ijọba apapọ, ṣugbọn awọn wọnyi gan-an kọ ni wọn ni ija yii, awon ti wọn ni ija yii gan-an ni awọn ilẹ Yoruba ati Ibo pẹlu ilẹ Hausa. Ija yii laarin awọn Hausa-Fulani pẹlu awọn to ku nilẹ Yoruba, ilẹ Ibo atawọn ti Naija Delta ni. Iyẹn laarin awọn ara Arewa (North), atawọn ara Guusu (South). Jide to n ṣejọba Eko, Wike to n ṣejọba Rivers, awọn mejeeji wa nile-ẹjọ pẹlu ijọba Buhari, wọn lawọn o fẹ ki wọn maa gb’owo ori lọdọ tawọn, ki wọn maa lọọ fi tọju wọn nilẹ Hausa, wọn lawọn o fẹ bẹẹ. Ba a ba ni ka wo o, ibeere kan naa lo wa nibẹ, iyẹn si ni pe iru irẹjẹ buruku wo ree. Nigba ti ẹ ba gbowo nilẹ Yoruba, ti ẹ n ko o lọọ fun wọn nilẹ Hausa. Ko daa loootọ!
Lati ọjọ ti wọn ti da Naijiria yii silẹ, ori irẹje ti wọn gbe e le niyi. Lord Lugard lo gbe e lori irẹjẹ bẹẹ, ijọba ilu oyinbo asiko naa si gba bẹẹ fun un. Tori ẹ l’Ọlorun o ṣe ni i foore fun ẹmi Lugard, Ọlọrun o ni i fi ẹmi ẹ lọkan balẹ, atubọtan ilẹ Biritain ko si ni i daa; awọn arọmọdọmọ Lugard aa daamu nigbẹyin aye wọn. O maa ri bẹẹ fun wọn, nitori idaamu to wa ni Naijiria bayii, idaamu to n ba gbogbo ẹda alawọ-dudu nitori pe Naijiria o toro, Lugard lo fa a, ijọba Britain lo fa a, ohun ti aburu tiwọn naa ṣe maa pada ba wọn niyẹn. Awọn ẹlomi-in le jokoo ki wọn ni ori baba yii o tun pe mọ ni, pe ti Britain tabi Lugard ba ṣe nnkan fun wa ni ọgọrun-un ọdun sẹyin, ṣe ko yẹ ki awa ti le yi i pada ni. Awọn to ba n sọ bẹẹ ko mọ ohun ti wọn n pe ni ipilẹ ni, bi ipilẹ ba ti bajẹ, ohun gbogbo to ba wa lori ẹ maa bajẹ ni!
Gbogbo ohun ti ẹ n sọ pe awọn Hausa-Fulani n ṣe fun wa loni-in yii, gbogbo iwa irẹjẹ buruku to gbilẹ lọdọ wọn loni-in yii, ipilẹ ti Lugard fi lelẹ ni, bo ṣe gbe Naijiria kalẹ ni, bi ijọba Britian ṣe ba a fọwọ si i pe ko gbe Naijiria kalẹ ni, ipo yii lawọn Hausa Fulani ko fẹ ko yipada, ohun to n ba nnkan wa jẹ titi doni yii niyi. Ẹmi gbese, ẹmi iwa apa, ẹmi ilọnilọwọgba, ka nigbagbọ pe tiwa nikan ni Naijiria, ka nigbagbọ pe ẹtọ wa ni lati gbowo lọwọ awọn ara Guusu ka waa fi tun Ariwa ṣe, awọn iwa buruku ti Lugard fi lelẹ fun wọn nilẹ Hausa ree, bo ṣe ṣe nigba to n ṣejọba nibi niyi, idi gan-an to si fi so ilẹ Hausa papọ mọ ilẹ Yoruba ati Ibo niyẹn. Ki i ṣe nitori ilọsiwaju kan, tabi nitori pe wọn fẹ ki ibi kan wa ti wọn maa maa pe ni Naijiria, nitori pe wọn fẹ ki wọn fi owo Guusu Naijiria tọju awọn ara ilẹ Hausa ni.
Ọun naa lo ba wa debi ti a wa yii o. Bẹẹ ọrọ kekere ti ko yẹ ko dija rara, ti ko tilẹ yẹ kẹni to ba fẹẹ ṣe olori ilu nla tori ẹ binu ni Lugard fi binu, to si tori ẹ ba ti odidi orilẹ-ede nla kan jẹ, o ko ifasẹyin ayeraye ba wọn. Lugard ki i ṣe ọmọwe, ko lọ si yunifasiti, iṣẹ ṣọja lo n ṣe, awọn ti wọn si koriira awọn to ba kawe ni. Idi ni pe lọdọ wọn naa lọhun-un, bo ti wu ki ṣọja kan lagbara tabi ko wa nipo to, awọn ti wọn ba kawe naa lo maa paṣẹ fun wọn, nitori awọn ni wọn maa maa ṣejọba. Tori bẹẹ, nigba ti Lugard de si Naijiria, ikoriira to kọkọ ni ni fawọn ọmọwe to wa l’Ekoo nigba naa, awọn ọmọ Yoruba ti wọn ti kawe rẹpẹtẹ, ti wọn si ti deeyan nla ni bii ọdun1900. Awọn yii o foju eeyan babara kan wo Lugard, wọn ṣaa mọ pe ṣọja lasan ni, oun atawọn ti wọn jẹ ọga ẹ lawọn jọ n ṣọrẹ niluu oyinbo wọn lọhun-un.
Awọn yii ki i gbọran si i lẹnu, to ba si ti paṣẹ kan, tabi to ba gbe eto ti ko nitumọ kan kalẹ, kia lawọn yii ti maa kọwe si London pe ki wọn kilọ fun un, tawọn yen aa si kilọ fun un loootọ, nitori awọn ọmọ Britain lawọn ti wọn wa l’Ekoo, ohun ti wọn ba fẹ nijọba gbọdọ ṣe fun wọn. Ṣebi ọkan lara awọn ilu oyinbo ni Eko nigba yii, ofin ti wọn n lo ni London ni wọn n lo nibẹ, iwa tawọn ọmọ London si n hu naa lawọn ọmọ Eko n hu, iyatọ diẹ lo wa laarin wọn. Tori bẹẹ ni nnkan o ṣe rọrun fun Lugard l’Ekoo, awọn ọmọwe ibẹ n fun un ni wahala gidi. Ki Lugard too de pada si Eko yii, o ti kọkọ wa si ilẹ Hausa, o ti wa gẹge bii ologun, to si ba wọn gba ilẹ lọwọ awọn ọba ibẹ, lẹyin naa, o ti waa da ṣọja akọkọ
silẹ fun Naijiria nilẹ Hausa nibẹ, o si ti mọ iwa awọn Hausa yii daadaa.
Nitori pe awọn Hausa ki i ṣe ọmọwe, ti wọn o mọwe kan ju Kewu lọ, to jẹ aṣẹ ti ọba wọn ba ti pa fun wọn ni wọn maa tẹle, o rọrun fun Lugard lati ba wọn ṣe, nitori to ba ti sọ fun ọba pe bayii ni kawọn eeyan ẹ ṣe o, bẹẹ ni wọn maa ṣe. Ṣugbọn awọn ara Eko o ri bẹẹ, ọba wo lo fẹẹ paṣẹ fun wọn! Alakọwe wo lo tiẹ fẹẹ tẹle aṣẹ ti ọba kan ba pa, paapaa ti aṣẹ naa o ba daa. Ọba funra ẹ n bẹru awọn ọmọwe, nitori o mọ pe ohun ti wọn le ba oun fa ko ni i daa. Ṣe iyẹn ni ọba kan maa waa sọ pe oun n paṣẹ fẹni kan. Oba ko le paṣẹ fara Eko, bẹẹ ni gomina kan tabi alaṣẹ oyinbo kan o le de ko maa ṣe giragira si wọn, wọn aa fi gege ba tiẹ jẹ ni. Gbogbo eyi bi Lugard ninu gan-an, nitori ija loni-in, asọ lọla ni, titi to fi rapala pada silẹ Hausa, ti wọn si fi i ṣe olori ijọba agbegbe naa. Niṣe ni ibẹ da bii igba to pada sile ẹ gan-an!
Lati igba ti Lugard ti de pada silẹ Hausa ni 1900 ni wahala to n ba Naijiria lọwọlọwọ yii ti bẹrẹ. Ki Lugard too de, ilẹ Hausa ki i lowo lọwọ, wọn ki i ṣowo ki wọn jere, wọn ki i ri kọbọ kan na ju owo ti ijọba ilu oyinbo ba fun wọn lọ, nigba to jẹ owo ti wọn yoo pa lọdọ wọn ko to lati gbọ bukaata wọn. Lugard lo bẹrẹ eto buruku, to kọkọ bẹrẹ si i yawo lọwọ awọn ara Guusu, to ni ki ijọba awọn ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba ya wọn lowo lati fi ṣe awọn iṣẹ ilu nilẹ Hausa. Ṣugbọn nigba ti gbese yii wa n pọ ju, ti owo ti wọn n fi ranṣẹ si i lati ilu oyinbo paapaa ko to lati na fawọn eeyan yii, Lugard bẹrẹ si i bẹ awọn olori ijọba ilu oyinbo wọn ki wọn ṣe ofin tuntun fawọn, ofin to maa le jẹ ki ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ni owo kan ti wọn aa maa fun ilẹ Hausa lọdọọdun lati fi ran wọn lọwọ, ki eto ọrọ-aje tiwọn naa le ni idagbasoke bii tiwọn.
Nibi ti Lugard ti bẹrẹ si i gbowo lọwọ ijọba awọn oyinbo ti wọn wa ni Guusu (South) ree, to fi n tun ilẹ Hausa (North) ṣe. Nibi yii ni iṣoro wa si ti bẹrẹ titi doni yii o. Bo ṣe ri bẹẹ, ma a tubọ ṣalaye ẹ fun yin lọsẹ to n bọ.